Àpótí Ìbéèrè
◼ Ṣó yẹ kí ìjọ tàbí ẹnì kan máa lo àmì tí àjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò lábẹ́ òfin?
Àmì tá à ń sọ yìí lè jẹ́ orúkọ tàbí àkọmọ̀nà tí wọ́n fi lè tètè dá àjọ kan mọ̀ yàtọ̀. Àmì Ilé Ìṣọ́ la fi ń dá Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania àtàwọn àjọ míì táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò mọ̀. Bíbélì tó wà ní ṣíṣísílẹ̀ ni àmì tó máa ń wà lórí lẹ́tà tí Christian Congregation of Jehovah’s Witnesses bá kọ. Àwọn àjọ míì táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò sì tún láwọn àmì tí wọ́n ń lò.
Torí náà, ìjọ tàbí ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ ṣe àmì tàbí orúkọ tí àjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò lábẹ́ òfin tàbí èyí tó jọ ọ́, sára Gbọ̀ngàn Ìjọba, pátákó ìsọfúnni, ìwé tí wọ́n fi ń kọ lẹ́tà, àwọn nǹkan àdáni àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ńṣe ni lílo àwọn àmì yìí lọ́nà bẹ́ẹ̀ máa ń fa ìdàrúdàpọ̀ lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ, àwọn ará, àtàwọn míì, tí wọn ò sì ní mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìjọ àti àjọ tá a ń lò lábẹ́ òfin. Bákan náà, ó tún lè mú kéèyàn rò pé orílé-iṣẹ́ tàbí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn ìsọfúnni kan ti wá, nígbà tọ́rọ̀ ò sì rí bẹ́ẹ̀.
A ò gbọ́dọ̀ ṣe àmì Ilé Ìṣọ́ tàbí èyí tó jọ ọ́ sára Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ kọ́, kódà kó jẹ́ ọ̀kan lára àjọ tí Watch Tower ń lò ló ni Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. A ò sọ pé káwọn ìjọ tó ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba tó ní irú àmì bẹ́ẹ̀ lọ mú un kúrò ní kíákíá o, tórí irú àtúnṣe bẹ́ẹ̀ lè gba kí wọ́n ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan, ó sì máa gba àkókò, ìsapá àti ìnáwó. Àmọ́, ẹ lè ṣe àtúnṣe yìí tó bá jẹ́ pé ohun tẹ́ ẹ máa ṣe níbẹ̀ kò ní pọ̀ jù. Láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kẹ́ ẹ dúró dìgbà tẹ́ ẹ fi máa ṣàtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí sanbọ́ọ̀dù yín.