Ǹjẹ́ Mò Ń Ṣe Tó Bó Ṣe Yẹ?
1. Àwọn nǹkan wo ló lè mú kí Kristẹni kan tó jẹ́ olóòótọ́ máa ṣàníyàn?
1 Ṣé o ti bi ara rẹ ní ìbéèrè yìí rí? Ó lè jẹ́ pé ara tó ti ń di ara àgbà, àìlera tàbí ojúṣe rẹ tó ń pọ̀ sí i nínú ìdílé ni kò jẹ́ kó o lè kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ bíi ti ìgbà kan, èyí sì ń mú kó o rẹ̀wẹ̀sì. Arábìnrin kan tó ní ọmọ mẹ́ta kọ̀wé pé, nígbà míì ọkàn òun máa ń dá òun lẹ́bi torí àkókò àti okun tóun fi ń bójú tó ìdílé òun kò jẹ́ kóun lè ṣe tó bóun ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ́ nípa ìwọ̀n tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́?
2. Kí ni Jèhófà ń retí pé ká ṣe?
2 Ohun Tí Jèhófà Retí Lọ́wọ́ Wa: Kò sí àní-àní pé gbogbo wa la máa fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ló máa ń wà láàárín ohun tá a máa ń fẹ́ ṣe àti ohun tí agbára wa gbé. Bó ṣe ń wù wá láti ṣe púpọ̀ sí i fi hàn pé a kò dẹra nù. Ó yẹ ká máa rántí nígbà gbogbo pé Jèhófà mọ ibi tí agbára wa mọ, kò sì béèrè ohun tó ju agbára wa lọ. (Sm. 103:13, 14) Kí ni Jèhófà ń retí pé ká ṣe? Ó fẹ́ ká sin òun tọkàntọkàn, ká sì ṣe gbogbo ohun tí agbára wa bá gbé.—Kól. 3:23.
3. Báwo la ṣe lè díwọ̀n ibi tí agbára wa mọ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́?
3 Kí ló máa jẹ́ ká lè mọ ohun tí agbára wa gbé? A lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká mọ ibi tí agbára wa mọ lóòótọ́. (Sm. 26:2) A lè wá ìrànlọ́wọ́ Kristẹni tá a fọkàn tán, tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀, tó sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tí kò ní fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nígbà tó bá ń sọ àwọn àtúnṣe tó yẹ ká ṣe. (Òwe 27:9) Tún rántí pé, á dáa ká máa ṣàyẹ̀wò ara wa látìgbàdégbà torí pé àwọn nǹkan máa ń yí pa dà.—Éfé. 5:10.
4. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn ìránnilétí látinú Bíbélì nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
4 Ojú Tó Yẹ Ká Máa Fi Wo Àwọn Ìránnilétí: Nígbà táwọn sárésáré bá ń sáré, àwọn òǹwòran á máa pariwo orúkọ àwọn tó ń sáré. Ìdí tí wọ́n sì fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni láti fún wọn níṣìírí kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí, kì í ṣe láti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn. Bákan náà, àǹfààní wa ni àwọn ìṣírí àti ìránnilétí tá a gbé ka Bíbélì, tá à ń rí gbà láwọn ìpàdé ìjọ àti nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, pé ká máa ‘wàásù ọ̀rọ̀ náà ní kánjúkánjú’ wà fún, kò túmọ̀ sí pé a kò ṣe tó bó ṣe yẹ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. (2 Tím. 4:2) Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa rántí ‘ìfẹ́ àti iṣẹ́’ wa, yóò sì bù kún wa, tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe.—Héb. 6:10.