ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/12 ojú ìwé 1
  • Máa Rí Ohun Rere Nínú Iṣẹ́ Àṣekára Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Rí Ohun Rere Nínú Iṣẹ́ Àṣekára Rẹ
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Tó Ń “So Èso Pẹ̀lú Ìfaradà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • ‘Ẹ Máa So Eso Púpọ̀’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • ‘Ọlọ́run Ló Ń Mú Kí Ó Dàgbà’!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kó Rẹ̀ Yín
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
km 11/12 ojú ìwé 1

Máa Rí Ohun Rere Nínú Iṣẹ́ Àṣekára Rẹ

1. Kí ló lè mú kí ìtara wa bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?

1 Jèhófà dá àwa èèyàn lọ́nà tó fi máa ń wù wá pé ká máa ‘rí ohun rere nínú iṣẹ́ àṣekára’ tá a bá ṣe. (Oníw. 2:24) Àmọ́ tí iṣẹ́ ìsìn wa kò bá méso jáde, ìtara wa lè bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù, ká sì wá dẹni tí kò láyọ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà. Kí la lè ṣe tá ò fi ní bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò tí kò tọ́ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

2. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní èrò tó tọ́ bí ọ̀pọ̀ àwọn tá a ń wàásù fún kò bá tiẹ̀ fetí sí wa?

2 Máa Ní Èrò Tó Tọ́: Ó yẹ ká máa rántí pé àwọn èèyàn díẹ̀ ló fetí sí ìwàásù Jésù, síbẹ̀ ó ṣe àṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Jòh. 17:4) Nínú àpèjúwe tí Jésù sọ nípa afúnrúgbìn, ó fi ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run wé irúgbìn, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé irúgbìn náà kò ní lè fìdí múlẹ̀ dáadáa lọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn. (Mát. 13:3-8, 18-22) Síbẹ̀, iṣẹ́ àṣekára wa máa ń yọrí sí rere.

3. Báwo la ṣe lè máa “so èso” bí ọ̀pọ̀ àwọn tá à ń wàásù fún kò bá tiẹ̀ fetí sí wa?

3 Bá A Ṣe Ń So Èso Púpọ̀: Jésù sọ pé àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì lóye rẹ̀ dáadáa máa “so èso.” (Mát. 13:23) Tí àlìkámà bá hù jáde tó sì dàgbà dáadáa, ó máa so àlìkámà tuntun tó máa ń wà nínú ṣírí àlìkámà. Kì í ṣe ṣírí àlìkámà náà ni Jésù pè ní èso bí kò ṣe àwọn kóró àlìkámà tuntun tí ṣírí náà mú jáde. Ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run tá à ń sọ fún àwọn èèyàn ni èso tí à ń so. Torí náà, kì í ṣe bí àwọn tó di ọmọ ẹ̀yìn lára àwọn tá a wàásù fún ṣe pọ̀ tó ló fi hàn pé Kristẹni kan ṣàṣeyọrí bí kò ṣe bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn léraléra tó. Yálà àwọn èèyàn fetí sí wa tàbí wọn ò fetí sí wa, wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run ni “ohun rere” tó ń fún wa láyọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. À ń tipa bẹ́ẹ̀ kópa nínú sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́. (Aísá. 43:10-12; Mát. 6:9) A sì ń gbádùn bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. (1 Kọ́r. 3:9) Iṣẹ́ ìwàásù yìí ni Bíbélì pè ní “èso ètè” wa, ó sì ń múnú Jèhófà dùn.—Héb. 13:15, 16.

4. Àwọn àṣeyọrí wo là ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa tá a lè má mọ̀?

4 Bá a ti ń ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a máa ń ṣe àṣeyọrí tó pọ̀ tá a lè má mọ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn tí Jésù parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ni àwọn kan lára àwọn tó gbọ́ ìwàásù rẹ̀ tó di ọmọ ẹ̀yìn. Bákan náà, ó lè pẹ́ kí irúgbìn Ìjọba Ọlọ́run tá a fún sọ́kàn ẹnì kan tó dàgbà. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè wá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn táwa ò sì ní í mọ̀. Ó dájú pé à ń ṣe àṣeyọrí tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa “bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀,” ká lè máa fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni wá.—Jòh. 15:8.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́