Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì—Jónà
1. Àwọn ìwà rere wo ni Jónà ní?
1 Kí ló máa ń kọ́kọ́ wá sí ẹ lọ́kàn tó o bá rántí wòlíì Jónà? Àwọn kan lè máa rò pé ojo tàbí ẹni tí kò láàánú àwọn èèyàn ni. Àmọ́, Jónà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó nígboyà, ó sì ṣetán láti kú nítorí àwọn èèyàn. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jónà?—Ják. 5:10.
2. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀ Jónà?
2 Ìrẹ̀lẹ̀: Jónà kọ́kọ́ pa iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an tì, ó sì sá lọ sí ibòmíì. Kò yà wá lẹ́nu pé ó sá lọ torí pé àwọn èèyàn mọ àwọn ará Ásíríà sí ẹhànnà èèyàn. Abájọ tí wọ́n fi ń pe Nínéfè ní “ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀.” (Náh. 3:1-3) Àmọ́ nígbà tí Jèhófà bá Jónà wí, tó sì tún rán an níṣẹ́ náà lẹ́ẹ̀kejì, ó fi hàn pé òun lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ torí pé ó gbà láti lọ jíṣẹ́ náà. (Òwe 24:32; Jónà 3:1-3) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti kọ́kọ́ sá lọ tẹ́lẹ̀, lọ́tẹ̀ yìí, ó ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ kó ṣe. (Mát. 21:28-31) Ṣé àwa náà á máa wàásù nìṣó bí wọ́n bá tiẹ̀ bá wa wí tàbí tí nǹkan ò bá fi bẹ́ẹ̀ rí bá a ṣe rò ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa?
3. Apá wo nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ló gba pé kó o nígboyà, kó o sì yọ̀ǹda ara rẹ?
3 Ìgboyà àti Ìyọ̀ǹda-Ara-Ẹni: Nígbà tí Jónà rí i pé ìpinnu tí òun ṣe láti sá lọ sí Táṣíṣì lè mú kí àwọn tó wà nínú ọkọ̀ yẹn pàdánù ẹ̀mí wọn, ó gbà láti kú kí àwọn yòókù lè wà láàyè. (Jónà 1:3, 4, 12) Nígbà tó fẹ́ lọ jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an sí ìlú Nínéfè, àárín gbùngbùn ìlú náà ló wọ̀ lọ kó lè rí ibi tó dáa dúró sí láti pòkìkí ìdájọ́ Ọlọ́run fún wọn. Wòlíì tó nígboyà tí kì í ṣojo ló lè ṣe irú ohun tí Jónà ṣe yẹn! (Jónà 3:3, 4) Àwa náà ńkọ́? A nílò ìgboyà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ká lè wàásù láìka àtakò sí. (Ìṣe 4:29, 31) Ìyọ̀ǹda-ara-ẹni ló sì máa jẹ́ ká lè lo àkókò wa àtàwọn ohun ìní wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù yìí.—Ìṣe 20:24.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká ronú jinlẹ̀ lórí àpẹẹrẹ àtàtà táwọn wòlíì Jèhófà fi lélẹ̀?
4 Ìgbàkígbà tó o bá ka ìtàn àwọn wòlíì Jèhófà, o máa jàǹfààní tó o bá fi ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn ro ara rẹ wò. Kó o bi ara rẹ pé: ‘Tó bá jẹ́ èmi ni, kí ni màá ṣe? Báwo ni mo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àtàtà tí wòlíì yìí fi lélẹ̀?’ (Héb. 6:11, 12) Lọ́jọ́ iwájú, àwọn àpilẹ̀kọ tó máa jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tá a rí kọ́ lára àwọn wòlíì míì tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.