ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/13 ojú ìwé 1
  • Kí Ló Ń Mú Ká Máa Wàásù?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Ń Mú Ká Máa Wàásù?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá a Ṣe Lè Nífẹ̀ẹ́ Ọmọnìkejì Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • “Nífẹ̀ẹ́ Aládùúgbò Rẹ Gẹ́gẹ́ Bí Ara Rẹ”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Báwo Ni Ìfẹ́ Rẹ Ṣe Gbòòrò Tó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ǹjẹ́ O “Nífẹ̀ẹ́ Aládùúgbò Rẹ Gẹ́gẹ́ Bí Ara Rẹ”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
km 5/13 ojú ìwé 1

Kí Ló Ń Mú Ká Máa Wàásù?

1. Ipa wo ni ìfẹ́ ń ní lórí iṣẹ́ ìwàásù wa?

1 Iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni iṣẹ́ tó dára jù lọ téèyàn lè ṣe láyé yìí. Iṣẹ́ yìí ń mú ká tẹ̀ lé àṣẹ méjì tó tóbi jù, ìyẹn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti aládùúgbò wa. (Máàkù 12:29-31) Ní tòótọ́, ìfẹ́ ló ń mú ká lè máa fi ìtara wàásù.—1 Jòh. 5:3.

2. Báwo ni iṣẹ́ ìwáàsù wa ṣe ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?

2 A Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà: Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n, la ṣe ń gbèjà rẹ̀. Ó ti tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ọdún báyìí tí Sátánì ti ń fi èké ba Jèhófà lórúkọ jẹ́. (2 Kọ́r. 4:3, 4) Èyí ló mú kí àwọn èèyàn máa rò pé Ọlọ́run máa ń dá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lóró nínú iná, pé mẹ́talọ́kan ni Ọlọ́run àti pé Ọlọ́run kò bìkítà nípa àwa èèyàn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló tiẹ̀ wá rò pé kò sí Ọlọ́run. Ìdí nìyí tó fi máa ń wù wá pé kí gbogbo èèyàn mọ òtítọ́ nípa Baba wa ọ̀run! Bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhofà ṣe ń ṣiṣẹ́ kára láti wàásù ń dùn mọ́ Ọlọ́run wa nínú, ó sì ń kó ìbànújẹ́ bá Sátánì.—Òwe 27:11; Héb. 13:15, 16.

3. Báwo ni iṣẹ́ ìwáàsù wa ṣe ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò?

3 A Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Aládùúgbò: Ìgbàkigbà tá a bá wàásù fún ẹnì kan, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Torí pé àkókò tó nira là ń gbé, àwọn èèyàn nílò kí wọ́n gbọ́ ìhìn rere. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló dà bí àwọn ará Nínéfè àtijọ́ tí “wọn kò mọ ìyàtọ̀ rárá láàárín ọwọ́ ọ̀tún wọn àti òsì wọn.” (Jónà 4:11) Iṣẹ́ ìwàásù wa la fi ń kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe kí wọ́n lè ní ojúlówó ayọ̀, kí ayé wọn sì dára. (Aísá. 48:17-19) Ó ń mú kí wọ́n nírètí. (Róòmù 15:4) Tí wọ́n bá gbọ́ ohun tá a bá wọn sọ, tí wọ́n sì fi ṣèwà hù, ó dájú pé Ọlọ́run á gbà wọ́n là.—Róòmù 10:13, 14.

4. Kí ni Jèhófà kò ní gbàgbé nípa wa?

4 Ìgbà gbogbo ni ọmọ rere máa ń ṣe ohun tí òbí rẹ̀ bá sọ. Ó sì máa ń fi hàn nígbà gbogbo pé òun nífẹ̀ẹ́ òbí òun. Bákan náà, tí ìfẹ́ Ọlọ́run bá jinlẹ̀ nínú wa, tá a sì nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa dénú, a ó máa lo àǹfààní tá a bá ní láti túbọ̀ wàásù nípa Ọlọ́run nígbà gbogbo, kò ní jẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. A ò sì ní jẹ́ kó rẹ̀ wá láé. (Ìṣe 5:42) Jèhófà kò ní gbàgbé irú ìfẹ́ yìí.—Héb. 6:10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́