Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì—Míkà
1. Ìbéèrè wo ló ṣeé ṣe kí Míkà ti ronú lé lórí, kí sì nìdí tá a fi lè sọ pé ìwàásù rẹ̀ kò já sí asán?
1 ‘Ìgbà wo ni ètò àwọn nǹkan búburú yìí máa wá sópin?’ Ó ṣeé ṣe kí wòlíì Míkà ti ronú lórí irú ìbéèrè yìí nígbà tó ń kéde ìdájọ́ Jèhófà lórí ìjọba Ísírẹ́lì àti Júdà. Síbẹ̀, ìwàásù rẹ̀ kò já sí asán. Àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà nípa Samáríà ṣẹ nígbà ayé Míkà, ìyẹn lọ́dún 740 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Míkà 1:6, 7) Nígbà tó yá, Jerúsálẹ́mù pa run lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Míkà 3:12) Lákòókò tiwa yìí, báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Míkà bí a ṣe ń dúró de ìgbà tí Jèhófà máa mú ìdájọ́ rẹ̀ wá?
2. Báwo la ṣe ń fi hàn pé a mú sùúrù bí a ti ń dúró de ọjọ́ Jèhófà, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?
2 Ẹ Mú Sùúrù: Míkà sọ pé: “Ní tèmi, Jèhófà ni èmi yóò máa wá. Dájúdájú, èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà mi.” (Míkà 7:7) Míkà ò kàn jókòó tẹtẹrẹ bó ṣe ń dúró de ìgbà tí òpin máa dé. Ó ń bá iṣẹ́ wòlíì rẹ̀ lọ. Bí a ṣe ń dúró de ọjọ́ Jèhófà, ó yẹ káwa náà máa kópa nínú “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.” (2 Pét. 3:11, 12) Bí Jèhófà ṣe ní sùúrù ń fáwọn èèyàn láǹfààní láti ronú pìwà dà. (2 Pét. 3:9) Nítorí náà, a fi ìtọ́ni Ọlọ́run sọ́kàn pé káwa náà mú sùúrù bíi ti àwọn wòlíì.—Ják. 5:10.
3. Kí nìdí tó fi yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀?
3 Gbára Lé Jèhófà Kó Lè Fún Ẹ Lókun: Iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún Míkà kò rọrùn, àmọ́ ohun tó fún un lókun tó fi lè ṣàṣeyọrí ni pé ó gbára lé Jèhófà. (Míkà 3:8) Abájọ tí Ọ̀rọ̀ Jèhófà fi rọ̀ wá pé ká gbára lé Ọlọ́run kó lè fún wa lókun. Ìwà ọ̀làwọ́ Ọlọ́run máa ń mú kó fún àwọn tó ti rẹ̀ lágbára kí wọ́n lè ṣe ojúṣe wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. (Sm. 84:5, 7; Aísá. 40:28-31) Ṣé ìwọ náà ti rí okùn gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run látìgbà tó o ti ń sìn ín? Ṣé o máa ń bẹ́ Jèhófà déédéé pé kó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó lè fún ẹ lókun?—Lúùkù 11:13.
4. Báwo ni ìgbé ayé Míkà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún wa lónìí?
4 Iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù sí Míkà nígbà ayé rẹ̀. Ó pinnu pé òun máa jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn oníwàkiwà ló yí i ká. Bíi ti Míkà, ojoojúmọ́ làwa náà ń rí ohun tó ń dán ìwà títọ́ wa wò. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a dúró lórí ìpinnu wa pé a ó “máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”—Míkà 4:5.