Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fi Ìgboyà Sọ̀rọ̀ Nípa Ìjọba Ọlọ́run
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Ká bàa lè tẹ̀ lé ìtọ́ni tó ṣe kedere tó wà ní 2 Tímótì 1:7, 8, ó ṣe pàtàkì pé ká máa fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè ní ìgboyà tá a bá fẹ́ sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run?
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Yan ẹnìkan tó o fẹ́ wàásù fún. Gbàdúrà sí Jèhófà kó o lè ní ìgboyà, kí o sì lo àǹfààní tó o bá ní láti sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run.