Bí A Ṣe Lè Máa Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́nà Tó Múná Dóko
1. Kí ni ojúṣe àwa tá à ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
1 Kò sí ẹni tó lè wá sin Ọlọ́run láìjẹ́ pé Jèhófà “fà á.” (Jòh. 6:44) Síbẹ̀ náà, ó yẹ kí àwa tá à ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ipa tiwa nínú ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti sún mọ́ Baba wọn ọ̀run. (Ják. 4:8) Èyí gba pé ká máa múra sílẹ̀. Kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó lè yé àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a ò kàn ní sọ pé kí wọ́n ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, ká sì béèrè ìbéèrè tó wà láwọn ìpínrọ̀ náà.
2. Àǹfààní wo ló máa tibẹ̀ jáde tá a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà tó múná dóko?
2 Tá a bá fẹ́ máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà tó múná dóko, ńṣe ló yẹ ká ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè (1) lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, (2) gba àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì gbọ́, kí wọ́n sì lè (3) fi àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n ń kọ́ sílò. (Jòh. 3:16; 17:3; Ják. 2:26) Ó lè gba ọ̀pọ̀ oṣù ká tó lè ran ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó tó lè ṣe àwọn nǹkan tá a mẹ́nu kàn yìí. Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ń ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn nǹkan tá a sọ yìí, èyí á jẹ́ kó ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, yóò sì ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún un.
3. Kí nìdí tí àwọn olùkọ́ tó jáfáfá fi máa ń béèrè ìbéèrè táá jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀?
3 Kí Ló Wà Lọ́kàn Ẹni Tí À Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?: Tá a bá fẹ́ mọ bí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lóye ohun tó ń kọ́ sí àti bí ìgbàgbọ́ tó ní nínú rẹ̀ ṣe rí, ká má ṣe sọ̀rọ̀ jù, ká sì máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. (Ják. 1:19) Ǹjẹ́ ó lóye ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀kọ́ tí ẹ̀ ń kọ́? Ǹjẹ́ ó lè ṣàlàyé ẹ̀kọ́ náà lọ́rọ̀ ara rẹ̀? Báwo làwọn ẹ̀kọ́ tó kọ́ náà ṣe rí lára rẹ̀? Ǹjẹ́ ó gbà pé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń kọ́ bọ́gbọ́n mu? (1 Tẹs. 2:13) Ṣe àwọn ohun tó ń kọ́ yé e débi pé ó máa gbé ìgbésí ayé rẹ lọ́nà tó bá ohun tó kọ́ mu? (Kól. 3:10) Tá a bá fẹ́ rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí, ó yẹ ká fọgbọ́n béèrè àwọn ìbéèrè táá jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, ká sì tẹ́tí sí i.—Mát. 16:13-16.
4. Kí ló yẹ ká ṣe tó bá ṣòro fún akẹ́kọ̀ọ́ kan láti lóye tàbí fi àwọn ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń kọ́ sílò?
4 Ó máa ń gba àkókò láti yí ìwà àwọn èèyàn àti ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ronú tó ti di bárakú fún wọn pa dà. (2 Kọ́r. 10:5) Tó bá jẹ́ pé akẹ́kọ̀ọ́ wa kò gba ohun tó kọ́ gbọ́ tàbí kò fi í sílò ńkọ́? Ó gba sùúrù kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ tó lè ṣiṣẹ́ lọ́kàn ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. (1 Kọ́r. 3:6, 7; Héb. 4:12) Tó bá sì jẹ́ pé akẹ́kọ̀ọ́ náà kò lóye ohun tí à ń kọ́ ọ tàbí tó ṣòro fún un láti fi àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń kọ́ sílò, ohun tó dára ni pé ká bọ́ sórí ẹ̀kọ́ míì dípò tí a ó fi máa fúngun mọ́ ọn. Bó pẹ́ bó yá, akẹ́kọ̀ọ́ náà yóò ṣe àwọn àyípadà tó bá yẹ tí a bá ń fi sùúrù àti ìfẹ́ kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.