ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NEHEMÁYÀ 12-13
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́ Lára Nehemáyà
Nehemáyà fìtara gbèjà ìjọsìn tòótọ́
Élíáṣíbù àlùfáà àgbà jẹ́ kí Tobáyà tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ àti alátakò ní ipa burúkú lórí òun
Élíáṣíbù gba Tobáyà láàyè láti máa gbé nínú yàrá ìjẹun tó wà nínú tẹ́ńpìlì
Nehemáyà da gbogbo àga àti tábìlì Tobáyà síta, ó sọ inú gbọ̀ngàn náà di mímọ́, ó sì jẹ́ kó pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀
Nehemáyà túbọ̀ ń mú àwọn nǹkan tí kò mọ́ kúrò ní Jerúsálẹ́mù