ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 60-68
Ẹ Yin Jèhófà, Olùgbọ́ Àdúrà
Tó o bá ṣèlérí fún Jèhófà, máa bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mú ìlérí rẹ ṣẹ
Tó o bá ń gbàdúrà nípa àwọn ìlérí tó o ṣe, Jèhófà á fún ẹ lókun kó o lè mú un ṣẹ
Bí a ṣe ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run ni ìlérí tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a ṣe
Hánà
Tó o bá sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún Jèhófà, ìyẹn á fi hàn pé o gbẹ́kẹ̀ lé e
Kí àdúrà wa lè nítumọ̀, a ní láti máa sọ gbogbo bí nǹkan ṣe rí lára wa fún Jèhófà
Tí àdúrà wa bá ṣe pàtó, ìdáhùn Jèhófà sí àdúrà wa á ṣe kedere sí wa
Jésù
Jèhófà ni Olùgbọ́ àdúrà gbogbo àwọn tó lọ́kàn rere
Jèhófà máa ń tẹ́tí sí “àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo” tó fẹ́ mọ̀ ọ́n, tí wọ́n sì fẹ́ fi tọkàntọkàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀
Ìgbàkigbà la lè gbàdúrà sí Jèhófà
Kọ̀nílíù
Àwọn nǹkan tí mo fẹ́ fi sínú àdúrà mi.