ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 69-73
Àwọn Èèyàn Jèhófà Jẹ́ Onítara fún Ìjọsìn Tòótọ́
Ó yẹ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé lóòótọ́ la jẹ́ onítara fún ìjọsìn tòótọ́
Dáfídì ní ìtara fún ìjọsìn Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀
Dáfídì kò gbà kí ẹnikẹ́ni bá Jèhófà díje tàbí kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà
Àwọn àgbàlagbà lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè jẹ́ onítara
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Dáfídì ló kọ sáàmù yìí. Ó sọ pé ó wu òun láti fún àwọn ìran tó ń bọ̀ ní ìṣírí
Àwọn òbí àtàwọn Kristẹni tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lè dá àwọn ọ̀dọ́ lẹ́kọ̀ọ́