ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 87-91
Má Ṣe Kúrò Ní Ibi Ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ
“Ibi ìkọ̀kọ̀” Jèhófà la ti ń rí ààbò nípa tẹ̀mí
Tá a bá fẹ́ máa gbé ní ibi ìkọ̀kọ̀ Jèhófà lónìí, a gbọ́dọ̀ ṣe ìyàsímímọ́, ká sì ṣe ìrìbọmi
Àwọn tí kò gbẹ́kẹ̀ lè Ọlọ́run kò mọ ibi ìkọ̀kọ̀ yìí
Fún àwọn tó wà ní ibi ìkọ̀kọ̀ Jèhófà, kò sí ohunkóhun tàbí èèyàn èyíkéyìí tó lè mú kí wọ́n má ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà tàbí nífẹ̀ẹ́ rẹ̀
“Pẹyẹpẹyẹ” náà fẹ́ dẹ pańpẹ́ mú wa
Àwọn ẹyẹ máa ń tètè fura gan-an, torí náà, ó máa ń ṣòro láti dẹ pańpẹ́ mú wọn
Àwọn pẹyẹpẹyẹ máa ń fara balẹ̀ kíyè sí ìṣesí àwọn ẹyẹ, wọ́n sì máa ń wá oríṣiríṣi ọ̀nà tí wọ́n á fi mú wọn
“Pẹyẹpẹyẹ náà,” Sátánì máa ń kíyè sí àwọn èèyàn Jèhófà, ó sì máa ń dẹ pańpẹ́ kó lè ba ipò tẹ̀mí wọn jẹ́
Mẹ́rin lára àwọn pańpẹ́ tó lè ṣekú pani tí Sátánì ń lò:
Ìbẹ̀rù Èèyàn
Kíkó Ọrọ̀ Jọ
Eré Ìnàjú Tí Kò Bójú Mu
Èdèkòyédè