ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÒWE 7-11
“Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọkàn-àyà Rẹ Yà Bàrá”
Àwọn ìlànà Jèhófà máa ń dáàbò bò wá. Àmọ́, kí wọ́n tó lè ṣe wá láǹfààní, a gbọ́dọ̀ fi wọ́n sínú ọkàn wa. (Owe 7:3) Ṣùgbọ́n bí ìránṣẹ́ Jèhófà èyíkéyìí bá lọ jẹ́ kí ọkàn òun yà bàrá, wẹ́rẹ́ ló máa kó sọ́wọ́ àwọn ètekéte Sátánì. Òwe orí 7 ṣàpèjúwe ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ tàn án jẹ. Kí la lè rí kọ́ nínú àṣìṣe tó ṣe?
Sátánì ń gbìyànjú ká lè ṣi àwọn ẹ̀yà ara márààrún tó wà fún ìmòye lò, ká lè tipa bẹ́ẹ̀ hùwà àìtọ́
Ọgbọ́n àti òye ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ronú lórí àbájáde ohun tá a fẹ́ ṣe, ká lè sá fún ohun tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́