ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb16 November ojú ìwé 3
  • Bíbélì Sọ Ohun Tí Ìyàwó Tó Dáńgájíá Máa Ń Ṣe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bíbélì Sọ Ohun Tí Ìyàwó Tó Dáńgájíá Máa Ń Ṣe
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Látọ̀dọ̀ Ìyá Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • ‘Ẹni Mímọ̀ Ni Ọkọ Rẹ̀ Jẹ́ Ní Àwọn Ẹnubodè’
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • “Orí Obìnrin Ni Ọkùnrin”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Coral—Ewu Ń Wu Ú, Ó sì Ń Kú
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
mwb16 November ojú ìwé 3

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÒWE 27-31

Bíbélì Sọ Ohun Tí Ìyàwó Tó Dáńgájíá Máa Ń Ṣe

Ìyá Lémúẹ́lì Ọba fún un ní ìsọfúnni tó ṣe tààrà nípa ojúṣe ìyàwó tó dáńgájíá nínú Òwe orí 31. Ìmọ̀ràn tó mọ́gbọ́n dání yìí jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ mọ ohun tó máa fi dá obìnrin tó dáńgájíà tó ṣeé fi ṣe ìyàwó mọ̀.

Ìyàwó tó dáńgájíá jẹ́ ẹni téèyàn lè fọkàn tán

Obìnrin kan láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì ń gbé oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀

31:10-12

  • Ó máa ń mú àbá tó wúlò wá nípa àwọn ohun tó ń lọ nínú ìdílé, síbẹ̀ ó máa ń tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀

  • Ọkọ rẹ̀ gbọ́kàn lé e pé ó máa ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, torí náà ọkọ rẹ̀ kì í sọ pé dandan ni kó kọ́kọ́ gba àṣẹ lọ́wọ́ òun kó tó lè ṣe ohunkóhun

Ìyàwó tó dáńgájíá máa ń ṣiṣẹ́ kára

Obìnrin kan láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì ń lọ nǹkan

31:13-27

  • Ó mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná, kì í sì í ṣe ju ara rẹ̀ lọ, kí àwọn ará ilé rẹ̀ lè máa wọṣọ tó bójú mu, kí wọn sì ní oúnjẹ tó ṣara lóore jẹ

  • Ó máa ń ṣiṣẹ́ kára, ó sì máa ń bójú tó agbo ilé rẹ̀ tọ̀sán tòru

Ó jẹ́ ẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀

Obìnrin kan ń gbàdúrà

31:30

  • Ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú rẹ̀

ǸJẸ́ O MỌ̀?

Ìlẹ̀kẹ̀ iyùn aláwọ̀ pupa gbayì gan-an lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Ó fani mọra, ó ṣọ̀wọ́n, ó sì ṣòro rí. Òkun Mẹditaréníà àti òkun Pupa ni wọ́n ti máa ń rí i. Ó sì ṣe pàtàkì gan-an fáwọn oníṣòwò.

Iyùn pupa

Bíbélì jẹ́ ká rí i pé bí góòlù, fàdákà àti sàfáyà ṣe jẹ́ ohun iyebíye, bẹ́ẹ̀ náà ni ìlẹ̀kẹ̀ iyùn jẹ́ ohun iyebíye.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé ìníyelórí obìnrin tó dáńgájíá “pọ̀ púpọ̀púpọ̀ ju ti iyùn.”​—Owe 31:10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́