ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb17 April ojú ìwé 5
  • Fún Àwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́ Níṣìírí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fún Àwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́ Níṣìírí
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Má Ṣe Gbàgbé Àwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • “Ẹ Pa Dà Sọ́dọ̀ Mi”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Ẹ Ṣèrànwọ́ fún Wọn Kí Wọ́n Lè Tètè Pa Dà Láìjáfara!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ẹ Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tó Ṣáko Lọ Kí Wọ́n Lè Pa Dà Sínú Agbo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
mwb17 April ojú ìwé 5

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Fún Àwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́ Níṣìírí

Olùṣọ́ àgùntàn kan fẹ́ gbé àgùntàn kan tó sọ nù

Lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ ló máa ń wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Àwọn náà ń sáré ìyè nígbà kan, àmọ́ oríṣiríṣi nǹkan ló lè fà á tí wọ́n fi wá dẹwọ́ báyìí, a sì sọ̀rọ̀ nipa díẹ̀ lára àwọn ìdí yìí nínú ìwé pẹlẹbẹ náà Jọ̀wọ́ Pa Dà Sọ́dọ̀ Jèhófà. (Heb 12:1) Síbẹ̀, àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ ṣì ṣeyebíye lójú Jèhófà, torí pé ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ló fi rà wọ́n. (Iṣe 20:28; 1Pe 1:18, 19) Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà?

Bó ṣe jẹ́ pé olùṣọ́ àgùntàn máa ń sapá gidigidi láti wá àgùntàn tó bá sú lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn alàgbà ṣe máa ń wá àwọn tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́, wọ́n sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. (Lk 15:4-7) Èyí fi hàn pé Jèhófà ń fìfẹ́ bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀. (Jer 23:3, 4) Kì í ṣe àwọn alàgbà nìkan ló yẹ kó máa fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ níṣìírí o, iṣẹ́ gbogbo wa ni. Tá a bá sapá láti fìfẹ́ hàn sí wọn tá a sì gba tiwọn rò, inú Jèhófà máa dùn, ó sì máa san wá lẹ́san rere. (Owe 19:17; Iṣe 20:35) Torí náà, ronú nípa àwọn tó o lè fún níṣìírí, má sì jáfara láti ṣe bẹ́ẹ̀!

Laura ń yọjú lójú fèrèsé, Abbey ń gbàdúrà, Abbey àti Laura gbá ara wọn mọ́ra, wọ́n sì jọ ya fọ́tò

WO FÍDÍÒ NÁÀ, Ẹ MÁA FÁWỌN ALÁÌṢIṢẸ́MỌ́ NÍṢÌÍRÍ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ni Abbey ṣe nígbà tó pàdé Ẹlẹ́rìí kan tí kò mọ̀ rí?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká sọ fún àwọn alàgbà tá a bá fẹ́ ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́?

  • Kí ni Abbey ṣe kó tó lọ sọ́dọ̀ Laura lẹ́ẹ̀kejì?

  • Báwo ni Abbey ṣe fi hàn pé òun ní ìforítì, sùúrù àti ìfẹ́ nígbà tó ń ran Laura lọ́wọ́?

  • Kí la rí kọ́ látinú àkàwé Jésù tó wà ní Lúùkù 15:8-10?

  • Kí ló jẹ́ àbájáde bí Abbey, àwọn alàgbà àtàwọn míì ṣe ran Laura lọ́wọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́