ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 1-5
Inú Ìsíkíẹ́lì Dùn Láti Kéde Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Nínú ìran kan tí Ìsíkíẹ́lì rí, Jèhófà fún un ní àkájọ ìwé kan, ó sì sọ pé kó jẹ ẹ́. Kí ni ìtúmọ̀ ìran yẹn?
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ yé Ìsíkíẹ́lì dáadáa. Tó bá ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ tó wà nínú àkájọ ìwé náà, ó máa wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an, èyí á sì jẹ́ kó nígboyà láti kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àkájọ ìwé náà dùn lẹ́nu Ìsíkíẹ́lì, torí pé inú rẹ̀ dùn sí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un