ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 28-31
Jèhófà San Ìlú Abọ̀rìṣà Kan Lẹ́san
Bí Jèhófà bá lè san ìlú abọ̀rìṣà lẹ́san fún iṣẹ́ tó ṣe, ó dájú pé ó máa san àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lẹ́san fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe!
OHUN TÍ BÁBÍLÓNÌ ṢE
Wọ́n sàga ti ìlú Tírè
OHUN TÍ MÀÁ ṢE
Irú ogun tẹ̀mí wo ni mò ń jà?
OHUN TÍ OJÚ ÀWỌN ARÁ BÁBÍLÓNÌ RÍ
Ọdún mẹ́tàlá ni wọ́n fi sàga ti ìlú Tírè, owó kékeré kọ́ nìyẹn sì ná wọn
Àwọn ọmọ ogun Bábílónì jìyà
Àwọn ará Bábílónì kò rí owó kankan gbà
ÀWỌN NǸKAN TÍ MO YÁÁFÌ
Àwọn nǹkan wo ni mo ti yááfì lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mi sí Jèhófà?
BÍ JÈHÓFÀ ṢE SAN BÁBÍLÓNÌ LẸ́SAN
Jèhófà fi Íjíbítì lé wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun ìfiṣèjẹ
BÍ JÈHÓFÀ ṢE SAN MÍ LẸ́SAN
Báwo ni Jèhófà ṣe san mí lẹ́san?