MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Àwọn Ànímọ́ Kristẹni Tó Yẹ Kó O Ní—Ìrẹ̀lẹ̀
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ:
Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn sún mọ́ Jèhófà.—Sm 138:6
Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ máa ń jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn.—Flp 2:3, 4
Ìparun ló máa ń gbẹ̀yìn àwọn agbéraga.—Owe 16:18; Isk 28:17
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
Ní kí ẹnì kan gbà ẹ́ nímọ̀ràn, kó o sì fi í sílò.—Sm 141:5; Owe 19:20
Máa ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ láti ran àwọn míì lọ́wọ́.—Mt 20:25-27
Má ṣe jẹ́ kí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tàbí ohun tó o mọ̀ ọ́n ṣe mú kó o máa gbéra ga.—Ro 12:3
Báwo ni mo ṣe lè fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn lọ́nà tó ga?
WO FÍDÍÒ NÁÀ, YẸRA FÚN OHUN TÓ LÈ BA ÌDÚRÓṢINṢIN RẸ JẸ́ —ÌGBÉRAGA, LẸ́YÌN NÁÀ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Tí wọ́n bá fún wa ní ìmọ̀ràn, báwo la ṣe máa ń ṣe?
Báwo ni àdúrà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní ìrẹ̀lẹ̀?
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?