MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Àwọn Ànímọ́ Kristẹni Tó Yẹ Kó O Ní—Ìgbàgbọ́
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ:
A gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ ká lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dáadáa.—Heb 11:6
Tá a bá gba àwọn ìlérí Ọlọ́run gbọ́, èyí á jẹ́ ká lè fara da àdánwò.—1Pe 1:6, 7
Tá ò bá ní ìgbàgbọ́, èyí lè mú ká dẹ́ṣẹ̀. —Heb 3:12, 13
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
Gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fún ẹ ní ìgbàgbọ́ sí i.—Lk 11:9, 13; Ga 5:22
Máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí o sì máa ṣàṣàrò lórí rẹ̀.—Ro 10:17; 1Ti 4:15
Máa ṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹni ìgbàgbọ́. —Ro 1:11, 12
Báwo ni mo ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ tèmi àti ti ìdílé mi túbọ̀ lágbára?
WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁA LÉPA OHUN TÓ LÈ MÚ KÓ O JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN—ÌGBÀGBỌ́, LẸ́YÌN NÁÀ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ: