ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÍKÀ 1-7
Kí Ni Jèhófà Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
Jèhófà mọ ibi tí agbára wa mọ, torí náà kì í sọ pé ká ṣe ohun tó pọ̀ ju agbára wa lọ. Lójú Ọlọ́run, ká tó lè sọ pé à ń ṣe ìjọsìn tòótọ́, ó ṣe pàtàkì pé ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn ará wa. Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba àwọn ẹbọ wa, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa ká sì bọ̀wọ̀ fún wọn.