November 27–December 3
NÁHÚMÙ 1–HÁBÁKÚKÙ 3
Orin 154 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Wà Lójúfò Kó O sì Máa Sin Jèhófà Nìṣó”: (10 min.)
[Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Náhúmù.]
[Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Hábákúkù.]
Hab 2:1-4—Tá a bá fẹ́ la ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà tó ń bọ̀ já, a gbọ́dọ̀ máa ‘fojú sọ́nà fún un’ (w07 11/15 10 ¶3-5)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Na 1:8; 2:6—Báwo ni wọ́n ṣe pa ìlú Nínéfè run? (w07 11/15 9 ¶2)
Hab 3:17-19—Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí nǹkan nira fún wa ṣáájú Amágẹ́dọ́nì àti nígbà tó bá ń lọ lọ́wọ́, kí ló dá wa lójú? (w07 11/15 10 ¶10)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Hab 2:15–3:6
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) hf—Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) hf—Nígbà tó o kọ́kọ́ wàásù fún ẹni náà, o ti fún un ní ìwé yìí. Ṣe ìpadàbẹ̀wò.
Àsọyé: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) w16.03 3-5—Àkòrí: Ṣé O Lè Ran Ìjọ Rẹ Lọ́wọ́?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Wà Lójúfò Kó O sì Máa Sin Jèhófà Nìṣó Tí Àyípadà Bá Ṣẹlẹ̀”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà A Wà Láàyè Nípa Tẹ̀mí, Bá A Tiẹ̀ Ṣí Lọ Síbòmíì.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 22 ¶1-7
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) Sọ fún àwọn ará pé àkòrí ìwé ìròyìn Jí! tá a máa lò lóṣù December ni “Ṣé Ayé Yìí Ti Bà Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe?” Tó bá fi máa di November 30, fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a máa jíròrò nípàdé lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀ á ti wà lórí JW Library. A rọ àwọn akéde pé kí wọ́n sapá gidigidi láti fún ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìwé ìròyìn yìí.
Orin 129 àti Àdúrà