MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀, Kó O Sì Mọ̀wọ̀n Ara Rẹ Bí I Ti Jésù
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ni ọkùnrin títóbi jù lọ tó gbé ayé rí, síbẹ̀ ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó sì mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ torí pé Jèhófà ló máa ń fògo fún. (Jo 7:16-18) Lọ́wọ́ kejì, Sátánì ló di Èṣù, tó túmọ̀ sí “Afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́.” (Jo 8:44) Ìwà burúkú Sátánì yìí náà làwọn Farisí máa ń hù, ìgbéraga wọn pọ̀ débi pé wọn máa ń fojú kéré àwọn tó nígbàgbọ́ nínú Mèsáyà. (Jo 7:45-49) Báwo la ṣe lè fìwà jọ Jésù tí wọ́n bá fún wa láǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan?
Kí ni Adé sọ tó fi hàn pé ó jẹ́ agbéraga?
Báwo ni Adé ṣe fi hàn pé òun lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?
Báwo ni Adé ṣe fún Báyọ̀ àti Kọ́lá níṣìírí?
Kí ni Arákùnrin Adú ṣe tó fi hàn pé kò mọ̀wọ̀n ara rẹ̀?
Kí ni Arákùnrin Adú ṣe tó fi hàn pé ó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀?
Ẹ̀kọ́ wo ni Fèyí rí kọ́ nípa bí Arákùnrin Adú ṣe fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀?