ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÒHÁNÙ 11-12
Máa Tu Àwọn Míì Nínú Bí I Ti Jésù
Kí ló mú kí ojú àánú tí Jésù ní ṣàrà ọ̀tọ̀?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn míì ló ti ṣẹlẹ̀ sí Jésù rí, síbẹ̀ ó máa ń fi ara rẹ̀ sípò wọn láti mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn
Jésù kì í tijú láti fi ìmọ̀lára rẹ̀ hàn ní gbangba
Kì í dúró dìgbà tí wọ́n bá sọ fún un kó tó ṣèrànwọ́ fáwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́