ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 1-3
Ọlọ́run Tú Ẹ̀mí Mímọ́ Sórí Ìjọ Kristẹni
Ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó wá sì Jerúsálẹ́mù fún àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni wá láti àwọn orílẹ̀-èdè míì. (Iṣe 2:9-11) Lóòótọ́ wọ́n ń tẹ̀ lé Òfin Mósè, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè yẹn ni wọ́n ti ń gbé láti kékeré. (Jer 44:1) Torí náà, òmíì nínú wọn lè má fi bẹ́ẹ̀ mọ èdè àwọn Júù àti bí wọ́n ṣe ń múra. Nígbà tí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) nínú wọn ṣe ìrìbọmi, bó ṣe di pé àwọn èèyàn láti oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti wá, síbẹ̀ ṣe ni ‘wọ́n ń pésẹ̀ nígbà gbogbo sí tẹ́ńpìlì pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan.’—Iṣe 2:46.
Báwo lo ṣe lè fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí . . .
àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín tó wá láti ìlú míì?
àwọn ará tó wá láti ìlú míì?