ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 KỌ́RÍŃTÌ 7-9
Ẹ̀bùn Ni Wíwà Láìní Ọkọ Tàbí Aya
Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ọ̀pọ̀ Kristẹni ló ti rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ló jẹ́ bí àwọn ṣe wà láì lọ́kọ tàbí aya torí ó fún wọn láyè láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn, ó jẹ́ kí wọ́n ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rẹ́, wọ́n sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.
Àwọn arákùnrin mẹ́ta ń wàásù jákèjádò Ọsirélíà lọ́dún 1937; akẹ́kọ̀ọ́yege Gílíádì kan dé sí Mẹ́síkò lọ́dún 1947
Arákùnrin kan ń wàásù ní Brazil; àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run ní Màláwì
ṢÀṢÀRÒ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Tí o kò bá tíì ṣègbéyàwó, báwo lo ṣe lè lo ẹ̀bùn tó o ní yìí dáadáa?
Báwo làwọn ará ìjọ ṣe lè ran àwọn tí kò tíì ṣe ìgbéyàwó lọ́wọ́, kí wọ́n sì fún wọn ní ìṣírí?