MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Kí Ni Jèhófà Máa Fẹ́ Kí N Ṣe?
Ká tó ṣe ìpinnu, ó kéré ni, ó pọ̀ ni, á dáa ká bi ara wa pé, ‘Kí ni Jèhófà máa fẹ́ kí n ṣe?’ Lóòótọ́ kò sí báa ṣe lè mọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn Jèhófà, àmọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ti jẹ́ ká mọ gbogbo ohun tá a nílò ká lè gbára dì fún “gbogbo iṣẹ́ rere.” (2Ti 3:16, 17; Ro 11:33, 34) Jésù fòye mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́, ó sì fi ìfẹ́ Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé rẹ̀. (Jo 4:34) Bíi ti Jésù, àwa náà lè ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè máa ṣe ìpinnu táá múnú Jèhófà dùn.—Jo 8: 28, 29; Ef 5:15-17.
WO FÍDÍÒ NÁÀ Ẹ MÁA FI ÒYE MỌ OHUN TÍ ÌFẸ́ JÈHÓFÀ JẸ́ (LE 19:18), KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ní ìgbésí ayé wa?
Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ yan orin tá a máa gbọ́?
Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ yan aṣọ tá a máa wọ̀ àti ìmúra wa?
Àwọn apá wo ní ìgbésí ayé wa ló tún yẹ ká ti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò?
Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe?
Kí ni àwọn ìpinnu tí mò ń ṣe ń sọ nípa àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà?