ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 PÉTÉRÙ 3-5
“Òpin Ohun Gbogbo Ti Sún Mọ́lé”
Láìpẹ́, ìpọ́njú ńlá irú èyí tí ò ṣẹlẹ̀ rí máa bẹ̀rẹ̀. Kí lá mú ká di ìṣòtítọ́ wa mú láìbọ́hùn nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú?
Máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kó o sì máa gba oríṣiríṣi àdúrà
Nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin látọkàn wá, kó o sì túbọ̀ sún mọ́ wọn
Túbọ̀ lẹ́mìí aájò àlejò
BI ARA RẸ PÉ, ‘Àwọn ọ̀nà wo ni mo lè gbà fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ àwọn ará tó wà ládùúgbò mi àti gbogbo ẹgbẹ́ ara lápapọ̀? Báwo sì ni mo ṣe lè túbọ̀ fẹ̀mí aájò àlejò hàn sí wọn?’