ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 PÉTÉRÙ 1-3
“Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn Dáadáa”
Jèhófà máa ṣe ìdájọ́ òdodo tó bá tó àkókò lójú rẹ̀. Ṣé bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa ń fi hàn pé à ń múra sílẹ̀ de ọjọ́ Jèhófà?
Kí ló túmọ̀ sí láti ní “ìwà mímọ́,” ká sì máa ṣe “iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run”?
A ò gbọ́dọ̀ máa lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe èyíkéyìí, ká sì ṣe tán láti gbèjà ìgbàgbọ́ wa
A gbọ́dọ̀ máa lọ́wọ́ nínú àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run déédéé, yálà ní gbangba tàbí láwa nìkan