Irú Ènìyàn Wo Ni Ó Yẹ Kí Ẹ Jẹ́?
1 Àkókò ìjíhìn súnmọ́lé fún gbogbo aráyé. Bibeli pè é ní “ọjọ́ Jehofa.” Ó jẹ́ àkókò tí a óò mú ìdájọ́ àtọ̀runwá ṣẹ sórí àwọn ẹni ibi; ó tún jẹ́ àkókò tí a óò dá àwọn olódodo nídè. Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó bá wà láàyè nígbà yẹn ní a óò pè láti jíhìn fún ọ̀nà tí wọ́n gbà gbé ìgbésí-ayé wọn. Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn, Peteru gbé ìbéèrè tí ń wádìí ọkàn dìde pé: “Irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́”? Ó tẹnumọ́ ìjẹ́pàtàkì ‘awọn ìṣe mímọ́ ní ìwà, awọn ìṣe ìfọkànsin Ọlọrun, àti fífi ọjọ́ Jehofa sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí,’ ní àfikún sí àìní láti wà ‘ní àìléèérí, ní àìlábààwọ́n, àti ní àlàáfíà.’—2 Pet. 3:11-14.
2 Àwọn Ìṣe Mímọ́ ní Ìwà àti Àwọn Ìṣe Ìfọkànsin Ọlọrun: Ìwà mímọ́ ní nínú àwọn iṣẹ́ àfiṣàpẹẹrẹ tí ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn ìlànà Bibeli. (Titu 2:7, 8) Kristian kan gbọ́dọ̀ yẹra fún àwọn ìwà ayé tí àwọn ìfẹ́-ọkàn onímọtara-ẹni-nikan, ti ẹran-ara ń sún ṣiṣẹ́.—Romu 13:11, 14.
3 “Ìfọkànsin Ọlọrun” ni a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “ìsora-ẹni-mọ́ Ọlọrun pẹ́kípẹ́kí, tí ń jẹyọ láti inú ọkàn-àyà tí ìmọrírì fún àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí ó fanimọ́ra ń sún ṣiṣẹ́.” Ìtara wa nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ jẹ́ ọ̀nà títayọ kan tí a lè gbà fi ànímọ́ yìí hàn. Ohun tí ń sún wa wàásù ju ìmọ̀lára ojúṣe lọ; ó jẹyọ láti inú ìfẹ́ tí ó jinlẹ̀ fún Jehofa. (Marku 12:29, 30) Bí irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ ti ń sún wa, a ń wo iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí àṣefihàn onítumọ̀ fún ìfọkànsìn tí a ní fún Ọlọrun. Níwọ̀n bí ìfọkànsin wa ti gbọ́dọ̀ wà déédéé, ìpín wa nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ yẹ kí ó wà déédéé. Ó yẹ kí ó jẹ́ apá pàtàkì kan nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìgbòkègbodò wa ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.—Heb. 13:15.
4 Fífi ọjọ́ Jehofa “sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí” túmọ̀ sí fífi í ṣàkọ́kọ́ nínú èrò wa ojoojúmọ́, ní ṣíṣàìrọ́ ọ sẹ́yìn sí ibi tí kò ṣe pàtàkì. Ó túmọ̀ sí fífi ire Ìjọba ṣàkọ́kọ́ nínú ìgbésí-ayé wa.—Matt. 6:33.
5 Ní Àìléèérí, ní Àìlábààwọ́n, àti ní Àlàáfíà: Gẹ́gẹ́ bí ara ogunlọ́gọ̀ ńlá náà, a ti ‘fọ aṣọ ìgúnwà wa, a sì ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa.’ (Ìṣí. 7:14) Nígbà náà, wíwà “ní àìléèérí” túmọ̀ sí pé nígbà gbogbo a gbọ́dọ̀ ṣọ́ ìgbésí-ayé wa mímọ́ tónítóní, tí a ti yà sí mímọ́ kí ó má bàa di èyí tí ayé kó èérí bá. A ń pa ara wa mọ́ “ní àìlábààwọ́n” nípa kíkọ̀ láti jẹ́ kí àwọn ìlépa ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì, ti àìṣèfẹ́ Ọlọrun ba ànímọ́ Kristian wa jẹ́. (Jak. 1:27; 1 Joh. 2:15-17) A ń fi hàn pé a ń gbé “ní àlàáfíà” nípa fífi “àlàáfíà Ọlọrun” hàn nínú gbogbo ìbálò wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.—Filip. 4:7; Romu 12:18; 14:19.
6 Bí a bá ṣàṣeyọrí nínú pípa ara wa mọ́ kúrò nínú ìsọdèérí ayé, a kì yóò “dáṣà ní àfarawé ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yìí,” tí Jehofa ti dẹ́bi fún. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn iṣẹ́ àtàtà wa yóò ṣèrànwọ́ fún àwọn mìíràn láti rí ìyàtọ̀ tí ó wà “láàárín ẹni tí ń sin Ọlọrun, àti ẹni tí kò sìn ín.”—Romu 12:2; Mal. 3:18.
7 A ń fojúsọ́nà fún pípésẹ̀ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ní àwọn oṣù díẹ̀ sí ìgbà tí a wà yìí, láìsí àníàní, oúnjẹ atunilára tẹ̀mí náà yóò mú ìfẹ́-ọkàn wa láti fi ìfọkànsin Ọlọrun hàn lágbára sí i. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹni titun ni ó ń ṣàjọpín ìfẹ́ àtọkànwá yìí. A lè jẹ́ ìbùkún fún wọn nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti kópa nínú iṣẹ́-ìsìn pápá ní August.
8 Nígba tí a bá ń gbìyànjú tọkàntọkàn láti máa bá ‘awọn iṣẹ́ àtàtà’ lọ, a ń gbé orúkọ Jehofa ga, a ń fún ìjọ lókun, àwọn ẹlòmíràn sì ń jàǹfààní. (1 Pet. 2:12) Ǹjẹ́ kí a máa fìgbà gbogbo jẹ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀.