MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Báwo Lo Ṣe Mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Tó?
Àtọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá, torí náà èrò rẹ̀ ló wà nínú Bíbélì. (2Pe 1:20, 21) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa lo Ìjọba rẹ̀ láti jẹ́ kó ṣe kedere pé Òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, àti pé láìpẹ́ nǹkan máa ṣẹnuure fún gbogbo èèyàn. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ tó fani mọ́ra tí Jèhófà Bàbá wa ọ̀run ní.—Sm 86:15.
Ohun tó mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yàtọ̀ síra. Àmọ́, ṣé à ń fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn yìí? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń kà á lójoojúmọ́, tá a sì ń fi àwọn ohun tá à ń kọ́ sílò nígbèésí ayé wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi hàn pé a mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bíi ti onísáàmù náà tó sọ pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o!”—Sm 119:97.
WO FÍDÍÒ NÁÀ WỌ́N MỌYÌ BÍBÉLÌ—DÍẸ̀ NÍNÚ ÌTÀN WILLIAM TYNDALE, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí nìdí tí William Tyndale fi túmọ̀ àwọn apá kan nínú Bíbélì?
Kí nìdí tí ìsapá rẹ̀ láti túmọ̀ Bíbélì fi gba àfíyèsí?
Báwo ni wọ́n ṣe dọ́gbọ́n kó ẹ̀dà ìtúmọ̀ Bíbélì tí Tyndale ṣe wọ orílẹ̀-èdè England?
Báwo lẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè fi hàn pé a mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?