MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Táwọn Míì Bá Ń Yìn Ẹ́
Nígbà míì, àwọn èèyàn lè gbóríyìn fún wa torí ohun tá a ṣe. Tó bá jẹ́ pé tọkàntọkàn ni wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn lè fún wa níṣìírí. (Owe 15:23; 31:10, 28) Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìyẹn kó sí wa lórí débi tá a fi máa ronú pé a sàn ju àwọn míì lọ.
WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN BÍI JÉSÙ—NÍGBÀ TÍ WỌ́N BÁ Ń YÌN Ọ́, LẸ́YÌN NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí làwọn nǹkan tó lè mú káwọn èèyàn máa gbóríyìn fún wa?
Báwo ni àwọn ará ṣe gbóríyìn fún Arákùnrin Ṣẹ́gun?
Báwo ni wọ́n ṣe yin Arákùnrin Ṣẹ́gun ju bó ṣe yẹ lọ?
Kí lo rí kọ́ nínú bí Arákùnrin Ṣẹ́gun ṣe fèsì?