ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 27-28
Ohun Tá A Rí Kọ́ Nípa Aṣọ Àlùfáà
Aṣọ táwọn àlùfáà máa ń wọ̀ rán wa létí pé ó ṣe pàtàkì ká máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ká jẹ́ mímọ́, ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká sì máa sá fún ohun tó máa tàbùkù sí Jèhófà.
Báwo la ṣe lè máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà?
Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ mímọ?
Báwo la ṣe lè lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká sì máa sá fún ohun tó máa tàbùkù sí orúkọ Jèhófà?