ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 29-30
Wọ́n Mú Ọrẹ Wá fún Jèhófà
Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kọ́ àgọ́ ìjọsìn, àtolówó àti tálákà ló láǹfààní láti mú ọrẹ wá fún iṣẹ́ náà. Báwo làwa náà ṣe lè mú ọrẹ wá fún Jèhófà lónìí? Ọ̀nà kan ni pé ká máa fi owó sínú àpótí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè, Bẹ́tẹ́lì àtàwọn ilé míì tá a yà sí mímọ́ fún ìjọsìn Jèhófà.
Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí tó bá dọ̀rọ̀ ká máa fi owó ṣètọrẹ fún ìjọsìn mímọ́?