ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb20 October ojú ìwé 3
  • Mọyì Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mọyì Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Jèhófà
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Eeṣe ti a Fi Nilati Ṣọra fun Ibọriṣa?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ẹ Ṣọra fun Gbogbo Oniruuru Ibọriṣa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ǹjẹ́ Ó Dá Ẹ Lójú Pé O Ní Àjọṣe Tó Dán Mọ́rán Pẹ̀lú Jèhófà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Kọ́ Àwọn Èèyàn Láti Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
mwb20 October ojú ìwé 3
Àwòrán: Ọkùnrin kan ń ṣe ohun tó máa jẹ́ kí àjọṣe òun àti Jèhófà lágbára sí i. 1. Ó ń gbàdúrà. Àmì kan lọ sókè. 2. Ó ń ka Bíbélì. Àmì kan wá sílẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mọyì Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Jèhófà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ kan. Lẹ́yìn tá a yara wa sí mímọ́ fún Jèhófà tá a sì ṣèrìbọmi, a túbọ̀ ń sapá kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa lè máa lágbára sí i. Ó lo Jésù Ọmọ rẹ̀ láti fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Jo 6:44) Ó sì máa ń gbọ́ àdúrà wa.​—Sm 34:15.

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run? Ohun kan ni pé, a gbọ́dọ̀ sá fún ohun tó máa mú ká dẹ́ṣẹ̀ bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá Jèhófà dá májẹ̀mú, wọ́n ṣe ère ọmọ màlúù, wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀. (Ẹk 32:​7, 8; 1Kọ 10:​7, 11, 14) Àwa náà lè bi ara wa pé: ‘Kí ni màá ṣe tí mo bá kojú ìdẹwò? Ṣé mò ń fi hàn pé mo mọyì àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà?’ Tí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà bá jinlẹ̀, àá máa sá fún ohunkóhun tí Jèhófà bá kórìíra.​—Sm 97:10.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÀJỌṢE RẸ PẸ̀LÚ JÈHÓFÀ BÀ JẸ́ (KOL 3:5), KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ni ojúkòkòrò?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká sá fún ojúkòkòrò àti ìbọ̀rìṣà?

  • Báwo ni ìṣekúṣe àti ìbọ̀rìṣà ṣe jọra?

  • Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tó ń múpò iwájú máa fiyè sí ohun tí ẹnì kejì wọn nílò?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́