ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb20 October ojú ìwé 5
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ṣé Jèhófà Ni Ọ̀rẹ́ Tẹ́ Ẹ Fẹ́ràn Jù Lọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ṣé Jèhófà Ni Ọ̀rẹ́ Tẹ́ Ẹ Fẹ́ràn Jù Lọ?
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó O Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ọlọ́run Ń Pè Ọ́ Pé Kí O Wá Di Ọ̀rẹ́ Òun
    Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
  • Ṣé Kí N Bo Àṣírí Ọ̀rẹ́ Mi?
    Jí!—2009
  • Èé Ṣe Tí Ọ̀rẹ́ Kòríkòsùn Mi Fi Kó Lọ Síbòmíràn?
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
mwb20 October ojú ìwé 5
Arákùnrin kan jókòó, ó sì dá kẹ́kọ̀ọ́.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́​—Ṣé Jèhófà Ni Ọ̀rẹ́ Tẹ́ Ẹ Fẹ́ràn Jù Lọ?

Gbogbo wa la máa ń fẹ́ ní ọ̀rẹ́ táá dúró tì wá nígbà ìṣòro, táá máa fàánú hàn sí wa, táá sì jẹ́ ọ̀làwọ́. Gbogbo ànímọ́ yìí ni Jèhófà ní. (Ẹk 34:6; Iṣe 14:17) Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà wa. Ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà gbogbo. (Sm 18:​19, 35) Ó máa ń dárí jì wá. (1Jo 1:9) Ọ̀rẹ́ gidi ni Jèhófà lóòótọ́!

Báwo lo ṣe lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà? Máa ka Bíbélì kó o lè túbọ̀ mọ Jèhófà. Máa sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún un. (Sm 62:8; 142:2) Fi hàn pé o mọyì àwọn ohun tó ṣe pàtàkì sí Jèhófà, ìyẹn àwọn nǹkan bíi Ìjọba rẹ̀, Ọmọ rẹ̀, àtàwọn ìlérí rẹ̀. Máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ fáwọn míì. (Di 32:3) Tó o bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ẹ̀yin méjèèjì á máa ṣọ̀rẹ́ títí láé.​—Sm 73:25, 26, 28.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ Ẹ̀YIN Ọ̀DỌ́​—‛Ẹ TỌ́ JÈHÓFÀ WÒ, KÍ Ẹ SÌ RÍ I PÉ Ó JẸ́ ẸNI RERE,’ KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Apá kan nínú fíìmù ‘Ẹ̀yin Ọ̀dọ́​—Ẹ Tọ́ Jèhófà Wò, Kí Ẹ sì Rí I Pé Ó Jẹ́ Ẹni Rere.’ Arábìnrin kan ń gbàdúrà kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í dá kẹ́kọ̀ọ́.

    Kí ló yẹ kó o ṣe kó o lè yara ẹ sí mímọ́, kó o sì ṣèrìbọmi?

  • Apá kan nínú fíìmù ‘Ẹ̀yin Ọ̀dọ́​—Ẹ Tọ́ Jèhófà Wò, Kí Ẹ sì Rí I Pé Ó Jẹ́ Ẹni Rere.’ Arákùnrin aṣáájú-ọ̀nà kan ń ka Bíbélì ní èdè Karen (S’gaw) fún ọkùnrin kan.

    Báwo làwọn ará nínú ìjọ ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa sin Jèhófà?

  • Apá kan nínú fíìmù ‘Ẹ̀yin Ọ̀dọ́​—Ẹ Tọ́ Jèhófà Wò, Kí Ẹ sì Rí I Pé Ó Jẹ́ Ẹni Rere.’ Arákùnrin kan ń bá arákùnrin àgbàlagbà kan ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí torí pé ó mọyì àwọn àgbàlagbà.

    Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe lè mú kí àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i?

  • Apá kan nínú fíìmù ‘Ẹ̀yin Ọ̀dọ́​—Ẹ Tọ́ Jèhófà Wò, Kí Ẹ sì Rí I Pé Ó Jẹ́ Ẹni Rere.’ Arábìnrin kan rin ìrìn wákàtí méjì láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ọmọbìnrin kan tó jẹ́ odi.

    Títí láé ni wàá máa gbádùn àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà!

    Àwọn iṣẹ́ wo lo lè ṣe nínú ètò Ọlọ́run, tó o bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?

  • Kí lohun tó o fẹ́ràn jù nípa Jèhófà?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́