ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb21 January ojú ìwé 11
  • Pinnu Láti Sin Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Pinnu Láti Sin Jèhófà
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìrìbọmi Ṣe Pàtàkì!
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ìrìbọmi​—Ohun Tó Yẹ Kí Gbogbo Kristẹni Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Béèyàn Ṣe Lè Dẹni Tó Yẹ Fún Ìrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìrìbọmi Ló Máa Fìdí Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run Múlẹ̀
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
mwb21 January ojú ìwé 11
Ọ̀nà tó ṣàpèjúwe àwọn ìgbésẹ̀ téèyàn máa gbé láti sin Jèhófà. Àwọn àmì tó wà lójú ọ̀nà yìí ṣàpẹẹrẹ àwọn nǹkan téèyàn máa ṣe, irú bí kéèyàn máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó máa lọ sípàdé, kó máa wàásù, kó sì ṣèrìbọmi.

Ibo lo dé lójú ọ̀nà ìrìbọmi?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Pinnu Láti Sin Jèhófà

Ṣé ọ̀dọ́ àbí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ò tíì ṣèrìbọmi ni ẹ́, ṣé ó wù ẹ́ kó o ṣèrìbọmi? Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣèrìbọmi? Ìdí ni pé ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi máa jẹ́ kó o ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (Sm 91:1) Ó tún máa jẹ́ kó o rí ìgbàlà. (1Pe 3:21) Kí ló máa jẹ́ kó o tóótun láti ṣèrìbọmi?

Ṣe ohun tá á mú kó dá ẹ lójú pé òótọ́ lohun tó ò ń kọ́. Tí nǹkan bá rú ẹ lójú, gbìyànjú láti ṣèwádìí nípa ẹ̀. (Ro 12:2) Tó o bá rí ohun tó yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí, tètè ṣàtúnṣe torí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà. (Owe 27:11; Ef 4:23, 24) Gbogbo ìgbà ni kó o máa gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́, á sì fún ẹ lókun. (1Pe 5:10, 11) Ohunkóhun tó o bá ṣe láti sin Jèhófà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìjọsìn Jèhófà lohun tó dáa jù lọ téèyàn lè fayé ẹ̀ ṣe!​—Sm 16:11.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ BÓ O ṢE LÈ ṢÈRÌBỌMI, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Ìṣòro wo làwọn kan ti borí kí wọ́n lè tóótun láti ṣèrìbọmi?

  • Kí lo lè ṣe tá á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ lágbára kó o lè ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà?

  • Kí ló mú káwọn kan pinnu láti ṣèrìbọmi?

  • Báwo ni Jèhófà ṣe ń bù kún àwọn tó bá pinnu pé òun làwọn máa sìn?

  • Kí ni ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi?

Nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ bá fẹ́ parí àsọyé ìrìbọmi, á ní kí àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi dìde dúró, kí wọ́n sì dáhùn àwọn ìbéèrè méjì yìí sókè ketekete:

Ṣé o ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ṣé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ṣé o sì gbà pé Jésù Kristi ni Jèhófà lò láti gbà wá là?

Ṣé o mọ̀ pé ìrìbọmi rẹ fi hàn pé o jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nínú ètò Ọlọ́run?

Táwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi bá dáhùn ketekete pé bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè yìí, ẹ̀rí nìyẹn pé wọ́n “kéde ní gbangba” pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà Jésù àti pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ pátápátá fún Jèhófà.​—Ro 10:9, 10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́