MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ìfẹ́ Ló Ń Mú Kí Jèhófà Bá Wa Wí
Wọ́n máa ń bá wa wí ká lè mọ ohun tó yẹ ká ṣe, àmọ́ nígbà míì ó lè gba pé kí wọ́n tọ́ wa sọ́nà tàbí kí wọ́n fìyà jẹ wá torí àṣìṣe tá a ṣe. Jèhófà máa ń bá wa wí ká lè máa jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó fẹ́. (Ro 12:1; Heb 12:10, 11) Ìbáwí máa ń dùn wá nígbà míì, àmọ́ tá a bá gbà á, á jẹ́ ká ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, Jèhófà á sì bù kún wa. (Owe 10:7) Kí ló yẹ kí ẹni tó ń báni wí àtẹni tí wọ́n ń bá wí fi sọ́kàn?
Ẹni tó ń báni wí. Ó yẹ káwọn alàgbà, àwọn òbí àtàwọn míì gbìyànjú láti finúure hàn tí wọ́n bá ń báni wí, kí wọ́n sì fìfẹ́ ṣe é bíi ti Jèhófà. (Jer 46:28) Kódà, tó bá gba pé kí wọ́n bá ẹnì kan wí lọ́nà tó múná, kí wọ́n ṣe é ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì àti lọ́nà tá fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹni náà.—Tit 1:13.
Ẹni tí wọ́n ń bá wí. Dípò tí àá fi máa ronú nípa bẹ́nì kan ṣe bá wa wí, ṣe ló yẹ ká gba ìbáwí náà, ká sì fi sílò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. (Owe 3:11, 12) Aláìpé ni gbogbo wa, torí náà a nílò ìbáwí, oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n sì lè gbà bá wa wí. Ó lè jẹ́ ohun tá a kà látinú Bíbélì tàbí ohun tá a gbọ́ nípàdé. Nígbà míì sì rèé, ó lè gba pé kí ìgbìmọ̀ onídàájọ́ bá wa wí. Àmọ́ tá a bá gba ìbáwí tá a sì fi sílò, ó máa ṣe wá láǹfààní, ìyẹn á sì jẹ́ ká wà láàyè títí láé.—Owe 10:17.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ “ÀWỌN TÍ JÈHÓFÀ NÍFẸ̀Ẹ́ LÓ MÁA Ń BÁ WÍ,” KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo ni nǹkan ṣe rí fún Canon nígbà tó wà ní kékeré, àmọ́ kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tó yá?
Báwo ni Jèhófà ṣe fìfẹ́ bá a wí?
Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa gba ìbáwí Jèhófà
Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i?