MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Fìfẹ́ Hàn Nínú Ìdílé
Ìfẹ́ ló máa ń so àwọn tó wà nínú ìdílé pọ̀. Tí ò bá sí ìfẹ́, ìdílé ò ní wà níṣọ̀kan, wọn ò sì ní fọwọ́sowọ́pọ̀. Báwo làwọn ọkọ, aya àtàwọn òbí ṣe lè máa fìfẹ́ hàn nínú ìdílé?
Tí ọkọ kan bá nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀, á máa ka ohun tó nílò sí pàtàkì, á máa tẹ́tí sí i, á sì máa gba tiẹ̀ rò. (Ef 5:28, 29) A máa pèsè ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí, á sì máa rí i pé òun ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé. (1Ti 5:8) Tí aya kan bá nífẹ̀ẹ́ ọkọ ẹ̀, á máa tẹrí ba fún un, á sì ní “ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀” fún un. (Ef 5:22, 33; 1Pe 3:1-6) Àwọn méjèèjì gbọ́dọ̀ máa dárí ji ara wọn ní fàlàlà. (Ef 4:32) Òbí tó bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀ máa jẹ́ kó dá ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lójú pé lóòótọ́ lòun nífẹ̀ẹ́ wọn, á sì máa kọ́ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Di 6:6, 7; Ef 6:4) Á gbìyànjú láti mọ ohun táwọn ọmọ náà ń kojú nílé ìwé àtohun tí wọ́n ń ṣe táwọn ọ̀rẹ́ wọn bá fẹ́ mú kí wọ́n ṣe ohun tí ò dáa. Tí ìfẹ́ bá wà nínú ìdílé, gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé náà lọ́kàn wọn máa balẹ̀.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁA FI ÌFẸ́ TI KÌ Í YẸ̀ HÀN NÍNÚ ÌDÍLÉ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo ni ọkọ tó nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀ á ṣe máa bọ́ ọ, tá sì máa ṣìkẹ́ ẹ̀?
Báwo ni ìyàwó tó nífẹ̀ẹ́ ọkọ ẹ̀ ṣe lè fi ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ hàn sí i?
Báwo làwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn ṣe lè máa kọ́ wọn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?