ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb22 January ojú ìwé 13
  • Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Sámúẹ́lì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Sámúẹ́lì
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Sámúẹ́lì Gbé Ìjọsìn Tòótọ́ Lárugẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ó “Ń Bá A Lọ Ní Dídàgbà Lọ́dọ̀ Jèhófà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ó “Ń Bá A Lọ ní Dídàgbà Lọ́dọ̀ Jèhófà”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ó Fara Da Ìjákulẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
mwb22 January ojú ìwé 13
Àwòrán: Fọ́tò Danny àti Sámúẹ́lì nínú fídíò “Ohun Tá A Rí Kọ́ Lára Sámúẹ́lì.” 1. Danny. 2. Sámúẹ́lì.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Sámúẹ́lì

Sámúẹ́lì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀. Nígbà tó wà ní kékeré, kò jẹ́ kí Hófínì àti Fíníhásì, ìyẹn àwọn ọmọ Élì kọ́ òun ní ìkọ́kúkọ̀ọ́. (1Sa 2:22-26) Jèhófà wà pẹ̀lú Sámúẹ́lì bó ṣe ń dàgbà. (1Sa 3:19) Kódà nígbà tó dàgbà, ó ṣì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀ kò ṣe bẹ́ẹ̀.​—1Sa 8:1-5.

Kí la lè kọ́ lára Sámúẹ́lì? Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọ ohun tó ò ń kojú àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹ. Ó lè jẹ́ kó o nígboyà. (Ais 41:10, 13) Tó o bá jẹ́ òbí, tí ọmọ ẹ ò sì ṣe dáadáa ńkọ́? Rántí pé Sámúẹ́lì ò lè fipá mú àwọn ọmọ ẹ̀ tó ti tójú bọ́ láti máa sin Jèhófà. Ó fọ̀rọ̀ náà sọ́wọ́ Jèhófà, ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti jẹ́ olóòótọ́, kó sì múnú Jèhófà Baba rẹ̀ ọ̀run dùn. A ò sì lè sọ, àpẹẹrẹ rẹ lè mú kọ́mọ ẹ pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ OHUN TÁ A RÍ KỌ́ LÁRA SÁMÚẸ́LÌ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Fọ́tò kan nínú fídíò “Ohun Tá A Rí Kọ́ Lára Sámúẹ́lì.” Sámúẹ́lì ń gbé igi nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì.

    Báwo ni Sámúẹ́lì ṣe fi hàn pé òun nígboyà nígbà tó wà ní kékeré?

  • Fọ́tò kan nínú fídíò “Ohun Tá A Rí Kọ́ Lára Sámúẹ́lì.” Danny lọ bá ẹ̀gbọ́n ẹ̀, ó sì sọ fún un pé ìgbésí ayé tó ń gbé ò dáa.

    Báwo ni Danny ṣe fi hàn pé òun nígboyà?

  • Fọ́tò kan nínú fídíò “Ohun Tá A Rí Kọ́ Lára Sámúẹ́lì.” Wòlíì Sámúẹ́lì ti dàgbà.

    Àpẹẹrẹ rere wo ni Sámúẹ́lì fi lélẹ̀ nígbà tó dàgbà?

  • Fọ́tò kan nínú fídíò “Ohun Tá A Rí Kọ́ Lára Sámúẹ́lì.” Danny àtàwọn òbí ẹ̀ ń bọ̀ láti òde ẹ̀rí.

    Jèhófà máa ń dúró ti àwọn tó bá pinnu láti ṣe ohun tó tọ́

    Àpẹẹrẹ rere wo làwọn òbí Danny fi lélẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́