MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Bópẹ́bóyá, Kò Sí Ìṣòro Tí Ò Ní Dópin
Ìṣòro máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni, pàápàá tó bá jẹ́ ìṣòro tí ò lọ bọ̀rọ̀. Dáfídì mọ̀ pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tóun máa bọ́ lọ́wọ́ Ọba Sọ́ọ̀lù, òun sì máa di ọba bí Jèhófà ṣe ṣèlèrí fún òun. (1Sa 16:13) Ìgbàgbọ́ tí Dáfídì ní yìí ló mú kó ní sùúrù, kó sì dúró de Jèhófà.
Tá a bá níṣòro, a sábà máa ń ronú nípa ọgbọ́n tá a lè dá tàbí ohun tá a lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà. (1Sa 21:12-14; Owe 1:4) Bó ti wù kó rí, àwọn ìṣòro kan kì í lọ láìka bá a ṣe sapá tó láti fi ìlànà Bíbélì yanjú wọn. Nírú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ní sùúrù dìgbà tí Jèhófà máa dá sí ọ̀rọ̀ náà. Láìpẹ́, Jèhófà máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ wá, á sì “nu gbogbo omijé” kúrò ní ojú wa. (Ifi 21:4) Yálà Jèhófà ló yanjú ìṣòro wa tàbí nǹkan míì ló ṣẹlẹ̀ tó mú kí ìṣòro náà lọ, ohun kan dájú: Bópẹ́bóyá, kò sí ìṣòro tí ò ní dópin. Ìrètí yìí lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ tá a bá níṣòro.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN ÈÈYÀN TÓ WÀ NÍṢỌ̀KAN NÍNÚ AYÉ TÓ PÍN YẸ́LẸYẸ̀LẸ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Ìṣòro wo làwọn ará wa ní gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà dojú kọ?
Kí ni wọ́n ṣe tó fi hàn pé wọ́n ní sùúrù, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn?
Kí ni wọ́n ṣe tó fi hàn pé “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù” ni wọ́n gbájú mọ́?—Flp 1:10