ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Kí Lo Máa Yááfì fún Jèhófà?
Jèhófà pàṣẹ pé kí Dáfídì kọ́ pẹpẹ kan ní ibi ìpakà Áráúnà (2Sa 24:18)
Áráúnà sọ pé òun máa fún Dáfídì ní ilẹ̀ àtàwọn ẹran tó máa fi rúbọ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ (2Sa 24:21-23)
Dáfídì sọ pé òun ò ní rú ẹbọ tí kò ná òun ní nǹkan kan sí Jèhófà (2Sa 24:24, 25; it-1 146)
Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda àkókò wa, okun wa àtàwọn nǹkan ìní wa fún ire Ìjọba náà. (w12 1/15 18 ¶8) Àwọn nǹkan wo lo lè fi ṣe àfojúsùn ẹ kó o lè túbọ̀ máa rú “ẹbọ ìyìn” sí Jèhófà?—Heb 13:15.