ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb22 September ojú ìwé 5
  • Jèhófà Fẹ́ Kí Ìgbéyàwó Wà Pẹ́ Títí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Fẹ́ Kí Ìgbéyàwó Wà Pẹ́ Títí
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Tó Lọ́kọ Tàbí Aya Àtàwọn Tí Kò Ní
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ìgbéyàwó Jẹ́ Ẹ̀bùn Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run Tó Nífẹ̀ẹ́ Wa
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Mímúra Sílẹ̀ fún Ìgbéyàwó Aláṣeyọrí
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run Lórí Ọ̀ràn Yíyan Ẹni Tí a Óò Fẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
mwb22 September ojú ìwé 5
Tọkọtaya kan jọ ń ṣiṣẹ́ ìwàásù.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jèhófà Fẹ́ Kí Ìgbéyàwó Wà Pẹ́ Títí

Ìdílé tó bá ní ayọ̀ máa ń mú ìyìn bá Jèhófà, ó sì máa ń jẹ́ kí ọkàn tọkọtaya balẹ̀. (Mk 10:9) Kí Kristẹni kan tó lè ní ìdílé aláyọ̀, kí ìgbéyàwó ẹ̀ sì dùn bí oyin, ó gbọ́dọ̀ fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò tó bá fẹ́ yan ẹni tó máa fẹ́.

Kó o tó ní àfẹ́sọ́nà, á dáa kó o “kọjá ìgbà ìtànná èwe,” ìyẹn ìgbà tí ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ máa ń lágbára, tó sì lè mú kéèyàn ṣi ìpinnu ṣe. (1Kọ 7:36) O lè fi àkókò tó o fi wà láìní ọkọ tàbí aya mú kí àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára, kó o sì mú kí ìwà rẹ dáa sí i. Tó o bá wá ṣègbéyàwó, àwọn ohun tó o ti kọ́ yìí á jẹ́ kó o lè di ọkọ tàbí aya rere.

Kó o tó pinnu láti fẹ́ ẹnì kan, ó yẹ kó o ṣe sùúrù, kó o sì fara balẹ̀ dáadáa kó o lè mọ “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn.” (1Pe 3:4) Tó o bá kíyè sí àwọn ohun kan tó kù-díẹ̀-káàtó, á dáa kíwọ àti àfẹ́sọ́nà ẹ jọ jókòó sọ ọ́. Bó o ṣe ń ronú nípa ìgbéyàwó, ohun tó yẹ kó jẹ ẹ́ lógún ni ohun tó o lè fún ẹnì kejì ẹ, kì í ṣe ohun tó o lè rí gbà lọ́wọ́ rẹ̀. (Flp 2:3, 4) Tó bá ti mọ́ ẹ lára láti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò kó o tó ṣègbéyàwó, á rọrùn fún ẹ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tó o bá ṣègbéyàwó, ìyẹn á sì jẹ́ kí ayọ̀ wà nínú ìdílè ẹ, kí ìgbéyàwó ẹ sì dùn bí oyin.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ BÓ O ṢE LÈ MÚRA SÍLẸ̀ FÚN ÌGBÉYÀWÓ—APÁ 3: ṢÍRÒ OHUN TÓ MÁA NÁ Ẹ,” KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo ni nǹkan ṣe rí láàárín arábìnrin náà àti Shane nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra sọ́nà?

  • Kí ni arábìnrin náà kíyè sí bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́?

  • Báwo làwọn òbí ẹ̀ ṣe ràn án lọ́wọ́, ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu wo ló sì ṣe?

Arákùnrin kan lè fi àwọn ìbéèrè yìí ṣàyẹ̀wò arábìnrin kan tó ń fẹ́ sọ́nà:

Àwọn ìwà rere wo ló ní? Kí ló ń ṣe tó fi hàn pé ire Ìjọba Ọlọ́run ló fi sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ̀? Ṣé ó ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́run ń fún wa? Ṣé àwọn ohun tó ń ṣe fi hàn pé ire àwọn míì jẹ ẹ́ lógún?

Arábìnrin kan lè fi àwọn ìbéèrè yìí ṣàyẹ̀wò arákùnrin kan tó ń fẹ́ sọ́nà:

Àwọn ìwà rere wo ló ní? Ṣé ó ka ìjọsìn Jèhófà àtàwọn ojúṣe ẹ̀ nínú ìjọ sí pàtàkì ju iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, owó, eré ìdárayá àti ìgbafẹ́ lọ? Báwo ló ṣe máa ń hùwà sáwọn ará ilé ẹ̀? Ṣé àwọn ohun tó ń ṣe fi hàn pé ire àwọn míì jẹ ẹ́ lógún?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́