MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ohun Tí Kò Ní Jẹ́ Ká Máa Fi Nǹkan Falẹ̀
Ẹni tó bá ń fi nǹkan falẹ̀ kì í ṣe ohun tó yẹ kó ṣe lásìkò tàbí kó máa sún nǹkan náà síwájú. Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ ní ti Jéhù. Nígbà tí Jèhófà rán an pé kó lọ pa àwọn ará ilé Áhábù, kò fi nǹkan falẹ̀ rárá. (2Ọb 9:6, 7, 16) Àwọn kan máa ń sọ pé: “Tó bá yá màá ṣèrìbọmi.” “Màá tó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì mi lójoojúmọ́.” “Màá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tí mo bá ti ríṣẹ́ gidi.” Bíbélì lè jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe tá ò fi ní máa fi nǹkan falẹ̀ nínú ìjọsìn wa.
Báwo làwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa jára mọ́ṣẹ́?