ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb23 March ojú ìwé 13
  • Bá A Ṣe Lè Lo Àwọn Fídíò Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Lo Àwọn Fídíò Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Fi Fídíò Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Máa Lo Fídíò Láti Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ipa Tí Àwọn Fídíò Tá A Fi Ń Jẹ́rìí Ń Ní Lórí Àwọn Èèyàn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Kí Ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
mwb23 March ojú ìwé 13
Arábìnrin kan ń fi fídíò “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?​—Èyí tó Gùn” han obìnrin kan lórí fóònù rẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bá A Ṣe Lè Lo Àwọn Fídíò Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Ètò Ọlọ́run ti ṣe àwọn fídíò mẹ́rin tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a lè lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Kí nìdí tá a fi ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn?

  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?​—Èyí tó Gùn. A ṣe fídíò yìí láti jẹ́ kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ Bíbélì láìka ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe sí. Àwọn tó bá wo fídíò náà a rí i pé inú Bíbélì làwọn ti lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé. Bákan náà, ó tún sọ ohun tí wọ́n lè ṣe tí wọ́n bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (èyí tó kúrú) Ohun tó wà nínú fídíò náà jọ ti èyí tó gùn, àmọ́ ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ṣe ṣókí. Ó máa dùn ń lò láwọn ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè fún ìjíròrò.

  • Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Fídíò yìí máa jẹ́ kó túbọ̀ wu àwọn èèyàn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a máa ń ṣe lọ́fẹ̀ẹ́, kí wọ́n sì rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọn. Bákan náà, ó tún sọ ohun tí wọ́n lè ṣe tí wọ́n bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

  • Ohun Tó O Máa Gbádùn Nínú Ẹ̀kọ́ Bíbélì Rẹ. A máa ń fi fídíò yìí han àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojú ìwé kejì nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!​—Ìjíròrò Látinú Bíbélì ni fídíò náà wà, a ṣì lè fi han àwọn èèyàn tá a bá ń jíròrò ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!​—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì. Fídíò náà sọ̀rọ̀ nípa ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ máa gbádùn àti ohun tó wà nínú ìwé náà.

Òótọ́ ni pé ìdí tá a fi ṣe fídíò kọ̀ọ̀kan la jíròrò lókè yìí, àmọ́ a ṣì lè fi han àwọn èèyàn tàbí ká fi ránṣẹ́ sí wọn nígbàkigbà tá a bá rí i pé ó yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. A rọ àwọn akéde pé kí wọ́n mọ ohun tó wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò yìí dáadáa, kí wọ́n sì máa lò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́