ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb23 July ojú ìwé 13
  • Àwọn Nǹkan Wo Lo Lè Fi Ṣe Àfojúsùn ní Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn Tó Ń Bọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Nǹkan Wo Lo Lè Fi Ṣe Àfojúsùn ní Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn Tó Ń Bọ̀?
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Gbé Àwọn Góńgó Tí Wàá Lépa ní Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn Tuntun Kalẹ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Báwo Ni Ọwọ́ Mi Ṣe Lè Tẹ Àwọn Àfojúsùn Mi?
    Jí!—2011
  • Fi Àwọn Ohun Tó Ò Ń lé Nípa Tẹ̀mí Yin Ẹlẹ́dàá Rẹ Lógo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
mwb23 July ojú ìwé 13
Ojú ọ̀nà kan tó jẹ́ ká rí àwọn àfojúsùn tẹ̀mí tá a lè ní. Àwọn àmì ojú ọ̀nà náà ṣàpẹẹrẹ, ìdákẹ́kọ̀ọ́, ìwàásù, àwọn ìwà tó yẹ Kristẹni àti ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Nǹkan Wo Lo Lè Fi Ṣe Àfojúsùn ní Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn Tó Ń Bọ̀?

Àfojúsùn tẹ̀mí ni ohunkóhun tá a bá ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ wa lè tẹ̀ torí ká lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tàbí ká lè múnú Jèhófà dùn. Àwọn àfojúsùn yìí máa ń jẹ́ ká túbọ̀ tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn wa. Tá a bá sì yááfì àkókò àti okun wa kọ́wọ́ wa lè tẹ̀ wọ́n, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. (1Ti 4:15) Látìgbàdégbà, ó yẹ ká máa ronú lórí àwọn ohun tá a fi ṣe àfojúsùn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ipò wa máa ń yí pa dà. Ohun tá a fi ṣe àfojúsùn nígbà kan lè má bá ipò wa mu mọ́ tàbí kọ́wọ́ wa ti tẹ̀ ẹ́, ìyẹn lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun míì tá a máa fi ṣe àfojúsùn.

Àsìkò tó dáa téèyàn lè ronú nípa ẹ̀ ni kí ọdún iṣẹ́ ìsìn tó bẹ̀rẹ̀. Ẹ ò ṣe jíròrò ohun tẹ́ ẹ lè ṣe nígbà ìjọsìn ìdílé yín, kẹ́ ẹ sì ronú nípa ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan lè ṣe àti ohun tẹ́ ẹ lè ṣe lápapọ̀ bí ìdílé?

Àwọn nǹkan pàtó wo lo máa fẹ́ ṣe tó bá dọ̀rọ̀ àwọn ohun tá a tò sísàlẹ̀ yìí, kí lo sì lè ṣe kọ́wọ́ ẹ lè tẹ̀ wọ́n?

Bíbélì kíkà, ìdákẹ́kọ̀ọ́, lílọ sípàdé, dídáhùn nípàdé.​—w02 6/15 15 ¶14-15

Iṣẹ́ ìwàásù.​—w23.05 27 ¶4-5

Àwọn ìwà tó yẹ Kristẹni.​—w22.04 23 ¶5-6

Àwọn nǹkan míì:

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́