MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Tí Ẹnì Kan Bá Ń Halẹ̀ Mọ́ Ẹ
Àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ni lè pa wá lára, kí wọ́n sì ṣe ohun tó máa mú kí inú wa bà jẹ́. Wọ́n tiẹ̀ lè máa ta kò wá torí pé à ń jọ́sìn Ọlọ́run, tá a bá sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà wá, ìyẹn lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Kí lo lè ṣe tí ẹnì kan bá ń halẹ̀ mọ́ ẹ?
Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ni wọ́n halẹ̀ mọ́, àmọ́ wọ́n borí àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ wọn torí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Sm 18:17) Bí àpẹẹrẹ, Ẹ́sítà fìgboyà sọ fún ọba nípa ohun búburú tí Hámánì tó ń halẹ̀ mọ́ àwọn Júù fẹ́ ṣe. (Ẹst 7:1-6) Kí Ẹ́sítà tó sọ fún ọba, ó gbààwẹ̀, ìyẹn sì fi hàn pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Ẹst 4:14-16) Jèhófà ràn án lọ́wọ́, ó sì dáàbò bo Ẹ́sítà àtàwọn èèyàn rẹ̀.
Ẹ̀yin ọ̀dọ́, tí ẹnì kan bá ń halẹ̀ mọ́ yín, ẹ bẹ Jèhófà pé kó ràn yín lọ́wọ́, kẹ́ ẹ sì sọ ìṣòro náà fún àgbàlagbà kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, irú bí àwọn òbí yín. Ó dájú pé Jèhófà máa ràn yín lọ́wọ́ bíi ti Ẹ́sítà. Kí lo tún lè ṣe tí ẹnì kan bá ń halẹ̀ mọ́ ẹ?
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÌGBÀ Ọ̀DỌ́ MI—OHUN TÓ O LÈ ṢE TÍ WỌ́N BÁ Ń HALẸ̀ MỌ́ Ẹ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Ẹ̀kọ́ wo làwọn ọ̀dọ́ lè rí kọ́ lára Charlie àti Ferin?
Kí làwọn òbí lè rí kọ́ látinú ohun tí Charlie àti Ferin sọ nípa báwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ tí ẹnì kan bá ń halẹ̀ mọ́ wọn?