ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb23 September ojú ìwé 11
  • Jèhófà Ń Gba Àwọn Tí Àárẹ̀ Bá Ẹ̀mí Wọn Là

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Ń Gba Àwọn Tí Àárẹ̀ Bá Ẹ̀mí Wọn Là
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Ìbànújẹ́ Kúrò Lọ́kàn Mi?
    Jí!—2010
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Jèhófà “Ń Mú Àwọn Tó Ní Ọgbẹ́ Ọkàn Lára Dá”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Ìbànújẹ́ Kúrò Lọ́kàn Mi?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
mwb23 September ojú ìwé 11

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jèhófà Ń Gba Àwọn Tí Àárẹ̀ Bá Ẹ̀mí Wọn Là

Gbogbo wa la máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ti pé inú ẹnì kan ò dùn kò túmọ̀ sí pé kò nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Ó ṣe tán, àwọn ìgbà kan wà tí inú Jèhófà náà ò dùn. (Jẹ 6:​5, 6) Àmọ́ tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni inú wa kì í dùn ńkọ́?

Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jèhófà fẹ́ kí inú wa máa dùn nígbà gbogbo. Ó mọ ìgbà tí inú wa ń dùn àtìgbà tínú wa ò dùn. Ó mọ ohun tó ń kó wa lọ́kàn sókè, àti bí nǹkan ṣe rí lára wa. (Sm 7:9b) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́ tí inú wa ò bá dùn tàbí tá a bá rẹ̀wẹ̀sì.—Sm 34:18.

Má ṣe jẹ́ kí èrò òdì gbà ẹ́ lọ́kàn. Tá a bá jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì gbà wá lọ́kàn, kì í ṣe pé a ò ní láyọ̀ nìkan, á tún ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Torí náà, a gbọ́dọ̀ dáàbò bo ọkàn wa, lédè míì, ká má gba èrò òdì láyè.—Owe 4:23.

Ẹ WO FÍDÍÒ ỌKÀN ÀWỌN ARÁ WA BALẸ̀ LÁÌKA Ẹ̀DÙN ỌKÀN SÍ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwọn nǹkan wo ni Nikki ṣe kí ẹ̀dùn ọkàn má bàa gbà á lọ́kàn?

  • Kí ló mú kí Nikki gbà pé á dáa kóun lọ rí dókítà?—Mt 9:12

  • Àwọn nǹkan wo ni Nikki ṣe tó fi hàn pé ó gbára lé Jèhófà?

“Ilé Ìṣọ́” No. 1 2023, tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìlera Ọpọlọ.”

Ṣé o mọ ẹnì kan tí Ilé Ìṣọ́ No. 1 2023 máa ṣe láǹfààní?

Àwọn nǹkan wo la lè ṣe tá ò fi ní jẹ́ kí èrò òdì gbà wá lọ́kàn?

(Mú èyí tí wàá fẹ́ túbọ̀ máa ṣe.)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́