MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Èrò Rẹ
Kì í ṣe ohun tá à ń sọ tàbí ṣe nìkan ló ń fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́, ó tún kan ohun tá à ń rò. (Sm 19:14) Torí náà, Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa ronú nípa ohunkóhun tó jẹ́ òótọ́, tó ṣe pàtàkì, tó jẹ́ òdodo, tó jẹ́ mímọ́, tó yẹ ní fífẹ́, tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, tó dára, títí kan ohunkóhun tó yẹ fún ìyìn. (Flp 4:8) Òótọ́ ni pé kò sí ohun tá a lè ṣe tí èròkerò kò fi ní máa wá sí wa lọ́kàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ tá a bá ń kó ara wa níjàánu, ó máa rọrùn fún wa láti fi èrò tó tọ́ rọ́pò irú èrò bẹ́ẹ̀. Tá a bá jẹ́ olóòótọ́ nínú èrò wa, ó máa hàn nínú bá a ṣe ń hùwà.—Mk 7:21-23.
Kọ àwọn èrò tó yẹ kó o yẹra fún sábẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà nísàlẹ̀ yìí: