ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp21 No. 1 ojú ìwé 8-9
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kì Í Dáhùn Àwọn Àdúrà Kan?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kì Í Dáhùn Àwọn Àdúrà Kan?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2021
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Sún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Àǹfààní Pàtàkì Ni Àdúrà Jẹ́
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Adura Awọn Wo Ni A Ndahun?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ǹjẹ́ Ó Tiẹ̀ Láǹfààní Tádùúrà Gbígbà Ń Ṣe?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2021
wp21 No. 1 ojú ìwé 8-9

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kì Í Dáhùn Àwọn Àdúrà Kan?

Inú Jèhófà Baba wa ọ̀run máa ń dùn láti gbọ́ àdúrà tá a fi òótọ́ inú gbà. Àmọ́ àwọn nǹkan kan wà tó lè má jẹ́ kó gbọ́ àwọn àdúrà wa. Kí ni àwọn nǹkan náà? Kí ló sì yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń gbàdúrà? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí.

Àwọn kan wà ní ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n ń ka àdúrà jáde nínú ìwé.

“Tí o bá ń gbàdúrà, má sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ.”​—Mátíù 6:7.

Jèhófà kò fẹ́ ká máa há àwọn àdúrà tá a fẹ́ gbà sórí tàbí ká máa kà wọ́n jáde nínú ìwé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ ká máa gbàdúrà sí òun látọkàn wá. Wo bó ṣe máa rí lára ẹ tí ọ̀rẹ́ ẹ kan bá ń lo ọ̀rọ̀ kan náà lójoojúmọ́ láti fi bá ẹ sọ̀rọ̀, ṣé kò ní sú ẹ? Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ látọkàn wá. Tá a bá fi ọ̀rọ̀ tó ti ọkàn wá gbàdúrà sí Ọlọ́run, ìyẹn á jẹ́ ká lè sọ ohun tó ń dùn wá lọ́kàn fún Bàbá wa ọ̀run.

Ọkùnrin kan tó fẹ́ ta tẹ́tẹ́ di tíkẹ́ẹ̀tì rẹ̀ mú, ó sì ń wòkè bí ẹni pé ó ń gbàdúrà.

“Nígbà tí ẹ sì béèrè, ẹ ò rí gbà torí ohun tí kò dáa lẹ fẹ́ fi ṣe.”​—Jémíìsì 4:3.

Ó dájú pé a ò ní retí pé kí Ọlọ́run dáhùn àdúrà wa tó bá jẹ́ pé ohun tá a mọ̀ pé kò fẹ́ là ń béèrè pé kó ṣe fún wa. Bí àpẹẹrẹ, tí ẹni tó ń ta tẹ́tẹ́ bá gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kóun ṣoríire, kóun sì rówó jẹ́, ṣé Jèhófà á dáhùn àdúrà yẹn? Rárá, torí Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún wa pe ojúkòkòrò àti ìgbàgbọ́ nínú “ọlọ́run oríire” kò dára. (Àìsáyà 65:11; Lúùkù 12:15) Ẹ ò rí i pé kò bọ́gbọ́n mu ká retí pé kí Jèhófà dáhùn irú àwọn àdúrà yẹn! Kí Ọlọ́run tó lè dáhùn àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ohun tá a béèrè bá ohun tó sọ nínu Bíbélì mu.

Àlùfáà ológun kan ń gbàdúrà fún àwọn ọmọ ogun.

“Ẹni tí kì í fetí sí òfin, àdúrà rẹ̀ pàápàá jẹ́ ohun ìríra.”​—Òwe 28:9.

Ní àkókò tí wọ́n kọ Bíbélì, Ọlọ́run kì í dáhùn àdúrà àwọn tí wọ́n bá ṣàìgbọràn sí òfin òdodo rẹ̀. (Àìsáyà 1:15, 16) Èrò Ọlọ́run kò tíì yí pa dà. (Málákì 3:6) Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run dáhùn àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ máa sa gbogbo ipá wa láti tẹ̀ lé àwọn òfin rẹ̀. Àmọ́ tá a bá ti ṣe ohun tó burú sẹ́yìn ńkọ́? Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé Jèhófà kò ní gbọ́ àdúrà wa ni? Rárá o! Ọlọ́run á fìfẹ́ dárí jì wá tá a bá ronú pìwà dà tá a sì ṣàtúnṣe tó yẹ láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.​—Ìṣe 3:19.

“Ẹnikẹ́ni tó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó wà àti pé òun ló ń san èrè fún àwọn tó ń wá a tọkàntọkàn.”​—Hébérù 11:6.

Obìnrin kan ń ka Bíbélì.

Àdúrà kì í ṣe ohun tó kàn ń mára tuni lásán nígbà ìdààmú. Ó jẹ́ ọ̀nà tá à ń gbà fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ó sì tún jẹ́ ara ọ̀nà tá à ń gbà jọ́sìn Ọlọ́run. Jémíìsì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn sọ pé téèyàn ò bá “máa fi ìgbàgbọ́ béèrè,” kó “má rò pé òun máa rí ohunkóhun gbà lọ́dọ̀ Jèhófà.” (Jémíìsì 1:6, 7) Ká tó lè ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ wá àyè ká sì sapá láti kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì ká lè mọ̀ ọ́n. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yẹn, á jẹ́ ká mọ ìfẹ́ rẹ̀, á sì jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé tá a bá gbàdúrà sí Ọlọ́run, á gbọ́ wa.

MÁ SỌ̀RÈTÍ NÙ!

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run máa ń dáhùn, ó ń gbọ́ àdúrà àìmọye èèyàn tó ń fòótọ́ ọkàn gbàdúrà, ó sì ń dáhùn àdúrà wọn. Bíbélì sọ àwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣe kí inú Ọlọ́run lè dùn sí àdúrà rẹ. Àpilẹ̀kọ tó kàn máa ṣàlàyé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́