ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w21 February ojú ìwé 25
  • Arábìnrin Kan Rẹ́rìn-ín Músẹ́!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Arábìnrin Kan Rẹ́rìn-ín Músẹ́!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Láti Ìgbà Èwa Wa ni A ti Rántí Ẹlẹ̀dàá Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Àwọn Abiyamọ Iṣẹ́ Tí Wọ́n Ń Ṣe Pọ̀ Púpọ̀
    Jí!—2002
  • Àǹfààní Tí Àtẹ Tó Ṣeé Tì Kiri Ti Ṣe Wá Kárí Ayé
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Ìfẹ́ Ni A Fi Ń Dá Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Mọ̀—Yẹra fún Ohun Tó Lè Ba Ìṣọ̀kan Jẹ́
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
w21 February ojú ìwé 25

Arábìnrin Kan Rẹ́rìn-ín Músẹ́!

Helen ń rẹ́rìn-ín bó ṣe dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ àtẹ ìwé. Àwọn obìnrin méjì ń kọjá lọ.

ÀWỌN obìnrin méjì kan jọ ń rìn ní agbègbè tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ajé nílùú Baguio City, lórílẹ̀-èdè Philippines. Bí wọ́n ṣe ń lọ, wọ́n rí àtẹ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ wọn ò yà. Arábìnrin Helen tó dúró síbi àtẹ náà rẹ́rìn-ín músẹ́ sí wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn obìnrin náà ò yà síbi àtẹ ìwé yẹn, ẹ̀rín tí Helen rín sí wọn múnú wọn dùn gan-an.

Nígbà táwọn obìnrin náà ń pa dà sílé, wọ́n rí àkọlé jw.org gàdàgbà tí wọ́n kọ sára Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Wọ́n rántí pé àkọlé yẹn náà ni wọ́n rí lára àtẹ ìwé níbi tí Helen dúró sí. Ṣe ni wọ́n bọ́lẹ̀ nínú bọ́ọ̀sì tí wọ́n wọ̀, tí wọ́n sì lọ wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ ìpàdé tí wọ́n lẹ̀ mọ́ ara géètì Gbọ̀ngàn Ìjọba náà.

Àwọn obìnrin méjì náà ń rẹ́rìn-ín nígbà tí wọ́n rí Helen ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Àwọn obìnrin méjèèjì lọ sí ìpàdé tó tẹ̀ lé e. Ǹjẹ́ ẹ mẹni tí wọ́n rí bí wọ́n ṣe dé Gbọ̀ngàn Ìjọba? Helen ni! Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n rántí pé òun ló rẹ́rìn-ín sí àwọn níbi àtẹ ìwé. Helen sọ pé: “Nígbà tí wọ́n wá bá mi, ẹ̀rù kọ́kọ́ bà mí torí mo ronú pé àbí mo ti ṣe nǹkan kan fún wọn ni.” Àmọ́, àwọn obìnrin náà ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Helen.

Àwọn obìnrin náà gbádùn ìpàdé yẹn, ara sì tù wọ́n níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n rí àwọn ará tó ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe lẹ́yìn ìpàdé, wọ́n béèrè bóyá àwọn lè fọwọ́ kún un. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan nínú àwọn obìnrin náà ò gbé Philippines mọ́, èkejì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé, ó sì ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí ló mú kí èyí ṣeé ṣe? Torí pé arábìnrin kan rẹ́rìn-ín músẹ́ ni!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́